Home ÀKỌ̀TUN Olóye Àlàó Akala fà mí gòkè láàrin àwọn olórin- Ayéfẹ́lẹ́
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - January 16, 2022

Olóye Àlàó Akala fà mí gòkè láàrin àwọn olórin- Ayéfẹ́lẹ́

Olóye Àlàó Akala fà mí gòkè láàrin àwọn olórin- Ayéfẹ́lẹ́

Ọrẹ Òtítọ́jù

Gbajúgbajà olórin Jùjú n-nì, Dókítà Yíinká Ayéfẹ́lẹ́, ti ṣàlàyé bí gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ nígbà kan rí, Ọtunba Christopha Adebayọ Alao-Akala ṣe fà á gòkè nídìí iṣẹ́ orin.

Nínú àtẹjáde tó fi ṣọwọ́ sáwọn oníròyìn n’Ibadan ló ti sọrọ náà láti ṣèdárò ikú Akala l’Ọjọbọ, tó kọjá.

Ayefẹlẹ, to jẹ oludasilẹ ileeṣẹ Redio Fresh FM to wa n’Ibadan, Abẹokuta, Eko ati Ado-Ekiti, sọ pe Akala lo mu oun goke nitori to mu oun mọ awọn ẹni giga lorilede yii.

“Mi o le kọ itan igbesi aye mi ki Ọtunba Akala ma wa laaye pataki nibẹ nitori awọn ni wọn mu mi mọ awọn eeyan nla nla titi dori igbakeji aarẹ orileede yii nigba kan ti wọn fi n pe mi sode ariya wọn lati waa kọrin”, bẹẹ l’Ayefẹlẹ sọ.

O ṣalaye siwaju pe “Akọsilẹ ti Ọlọrun ti kọ pe mo maa jẹ eeyan pataki laye, Ọtunba Akala jẹ ọkan ninu awọn ti Ọlọrun lo fun mi lati mu ala naa wa si imuṣẹ nitori ipa ribiribi ti wọn ti ko ninu aye mi ati bi wọn ṣe mu mi mọ awọn eeyan giga giga laye.

“Awọn l’Ọlọrun lo fun mi ti mo fo di olorin ti ileeṣẹ aarẹ yan laayo to fi jẹ pe emi l’Alhaji Atiku Abubakar ati idile ẹ maa n pe waa kọrin nibi ariya yoowu ti wọn ba fẹẹ ṣe.

“Nitori naa, ẹdun ọkan gidi niku Ọtunba Akala jẹ fun emi ati idile mi. Iroyin iku wọn jẹ iṣẹlẹ to ṣoro fun mi lati pa mọra paapaa”.

O waa ṣadura fun oloogbe naa lati ri ijọba ọrun wọ, bẹẹ lọ gbadura fun ẹbi oloogbe pe Ọlọrun yoo duro ti wọn ati pe ọjọ gbogbo wọn yoo dalẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo

Ó yẹ kí Orílẹ̀ yìí gba ọlọ́pàá síi, kí á pèsè ohun ààbò ogun tiwantiwa–Ọsinbajo Ọrẹ …