Home ÀKỌ̀TUN Nítorí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀, àwọn aláṣẹ Fásitì KWASU lé olùkọ́ kan dànù
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - December 7, 2021

Nítorí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀, àwọn aláṣẹ Fásitì KWASU lé olùkọ́ kan dànù

Nítorí ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀, àwọn aláṣẹ Fásitì KWASU lé olùkọ́ kan dànù

Ọrẹ Òtítọ́jù

Àwọn aláṣẹ Fásitì KWASU (Kwara State University), Malete, ti lé olùkọ́ kan, Pẹlumi Adewale, dànù,pẹ̀lú ẹ̀sùn pé ó fẹ́ fipá bá akẹ́kọ̀ọ́ kan, Tosin Adegunsoye, lò pọ̀ nílé-ẹ̀kọ́ ọ̀hún.

Ọjọ Aje, ọṣẹ yii, ni Ọga agba ni Fasiti KWASU, Ọjọgbọn Mustapha Akanbi, fi iroyin naa lede fun awọn oniroyin nibi ipade akọroyin ti ọga agba ọhun pe lati fi sami ayẹyẹ ikẹkọọ-jade awọn akẹkọọ ti wọn n jade lọdun yii, ẹlẹẹkẹjọ ati ikẹsan-an iru ẹ.

Akanbi ni awọn ti le Adewale danu, o si ti kuro lara ọṣiṣẹ ile-ẹ̀kọ́ KWASU, tori pe o fẹẹ sọ ilé-ẹ̀kọ́ náá ní orúkọ burúkú. Ní báyìí, àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ti tẹ́wọ́ gba ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, wọ́n sì ti gbé ọkùnrin náà lọ sí ilé-ẹjọ́.

Ọjọ kọkanla, oṣu kẹsan-an, ni wọn wọ Adewale lọ siwaju ile-ẹjọ Majistreeti kan niluu Ilọrin, fẹsun ifipabanilopọ ati iwa ọdaran miiran to fara pẹ ẹ, ninu eyi ti wọn ni Adewale pe Tosin Adegunsoye to jẹ akẹkọọ-binrin, to si sọ fun un pe to ba fẹ yege idanwo nibi iṣẹ rẹ, ko wa si inu yara olukọ naa to wa ni Opopona Taoheed, ni Basin, niluu Ilorin, nibi ti yoo ti ni ibalopọ pẹlu rẹ, ti yoo si fun un ni ibeere ati idahun, ti ọmọbinrin ọhun yoo fi le tun idanwo rẹ ṣe. Ṣe oun ko kuku mọ pe Adegunsoye ti dẹ panpẹ kalẹ, to si mu Adewale lọrun ọwọ.

Onidaajọ Ibrahim Mohammed, gba beeli Adewale pẹlu ẹgbẹrun lọna igba Naira, to si sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kẹjọ, oṣu Kejila, ọdun yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé Ọrẹ Òtítọ́jù Nítorí à…