Home ÀKỌ̀TUN Bíọ́dún lu Mukaila pa n’Idiroko, nítorí àádọ́ta Náírà
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - December 7, 2021

Bíọ́dún lu Mukaila pa n’Idiroko, nítorí àádọ́ta Náírà

Bíọ́dún lu Mukaila pa n’Idiroko, nítorí àádọ́ta Náírà

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ẹ̀ṣẹ́ ń pààyàn lóòótọ́, tó bá bá a níbi tó lágbárá. Irú àwọn ẹ̀ṣẹ́ burúkú bẹ́ẹ̀ ló jọ pé Biọdun Adebiyi, ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ( 32), fi pa ọmọkùnrin kan, Mukaila Adamu, ẹni ọgbọ̀n ọdún (30), lágbègbè Ajégunlẹ, n’Idiroko, nítorí ṣéńjì àádọ́ta Náírà tó fẹ́ gbà lọ́wọ́ ọkùnrin náá.

Ọjọ Aiku, ọjọ karun-un, oṣu kejila yii, niṣẹlẹ naa waye. DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fi sita lọjọ Aje, ṣalaye pe Baba Mukaila to ku lo lọọ fẹjọ sun ni teṣan Idiroko, pe ni nnkan bii aago meji ọsan ọjọ Sannde naa ni Biọdun wa ra siga lọwọ ọmọ oun, Mukaila, bo si ti ra a tan lo ba tiẹ lọ.

Baba Mukaila tẹsiwaju pe afi bo ṣe di nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ Sannde naa ti Biọdun tun de, to ni oun fẹẹ gba ṣenji aadọta naira lọwọ ọmọ oun.

Ọrọ ṣenji wazo naa lo dija laarin wọn bi baba yii ṣe wi, lo ba di pe Biọdun bẹrẹ si i lu ọmọ oun bii ko ku, to n ku u lẹṣẹẹ gidi. Awọn ẹṣẹ agbara naa lo jẹ ki Mukaila ṣubu lulẹ, ti wọn si sare gbe e lọ sileewosan, nibi tawọn dokita ti sọ fun wọn pe ẹmi ti bọ lara rẹ.

Awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun mu Biọdun to n gbe l’Ojule karundinlogoji, Opopona Ọladun, Ikọtun, nipinlẹ Eko, Idiroko to ti lọọ daran naa ni wọn ti mu un, bẹẹ ni wọn ti gbe oku Mukaila lọ si mọṣuari, wọn ni wọn yoo ṣe ayẹwo fun un.

Wọn ti gbe Biọdun funra ẹ lọ sẹka ti wọn ti n ri si ọrọ awọn apaayan, nibi ti wọn yoo ti towe rẹ lọ sile-ẹjọ

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé Ọrẹ Òtítọ́jù Nítorí à…