Home ÀKỌ̀TUN Ilé-ẹjọ́ pàṣẹ fún ìjọba Ọ̀ṣun láti dáwọ́ dúró lórí yíyan Olúfọ́n tuntun Òṣogbo
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - December 6, 2021

Ilé-ẹjọ́ pàṣẹ fún ìjọba Ọ̀ṣun láti dáwọ́ dúró lórí yíyan Olúfọ́n tuntun Òṣogbo

Ilé-ẹjọ́ pàṣẹ fún ìjọba Ọ̀ṣun láti dáwọ́ dúró lórí yíyan Olúfọ́n tuntun
Òṣogbo

Ọrẹ Òtítọ́jù

Adájọ́ ilé-ẹjọ́ gíga kan nílùú Òṣogbo ti pàṣẹ pé kí ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ kan káwọ́ ró lórí yíyan Olúfọ́n ti ìlú Ifọ́n Orolu tuntun.
Alhaji Ọmọọba Sulaiman Akinyọọye, Ọmọọba Peter Oluwọle Akinyọọye, Ọmọọba Jide Akinlaja Akinyọoye, Ọmọọba Muideen Ọlarinde ati Ọmọọba Muideen Akinloye lati idile Morohunfolu nílé ọlọ́mọọba Ọláọjọ ni wọ́n gbé ẹjọ́ náà lọ sí kóòtù.

Awọn ti wọn si pe lẹjọ ni Ọmọọba Wahabi Oyegbile (latidile Ọdunolu ninu ile ọlọmọọba Ọlaọjọ), Gomina ipinlẹ Ọṣun, kọmiṣanna feto idajọ nipinlẹ Ọṣun, kọmiṣanna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ ati alaga ijọba ibilẹ Orolu.

Awọn yooku ni Oloye Agba Oyetunde Oyetunji to jẹ Eesa Ifọn Ọṣun, Oloye Agba Amusa Majoyegbe Ọlaawin to jẹ Aajẹ Ifọn Ọṣun, Oloye Agba Julius Oyeleke to jẹ Elesi ti Ifọn Ọṣun, Oloye Agba Moshood Adeoye to jẹ Ikọlaba ti Ifọn Ọṣun, Oloye Agba Adamọ Akintunde yo jẹ Ẹjẹmu ti Ifọn Ọṣun ati Oloye Agba Lamulatu Afọlabi to jẹ Iyalode ti Ifọn Ọṣun.

A oo ranti pe ijọba ipinlẹ Ọṣun ti kọ lẹta si ile ọlọmọọba Ọdunolu lati fi orukọ ẹni ti yoo di Olufọn ranṣẹ, eleyii ti awọn idile Ọlaọjọ ri bii ọna lati fi ẹtọ wọn du wọn.
Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, ṣe nijọba gboju kuro lara akọsilẹ ilana jijẹ ọba ilu naa, eleyii ti wọn ṣatunṣe si lọdun 1988, ṣugbọn ti wọn fẹẹ lo ti ọdun 1979, idi si niyi ti wọn fi gba kootu lọ.

Ninu idajọ rẹ ,Onidaajọ A. O. Oyebiyi sọ pe ijọba ipinlẹ Ọṣun atijọba ibilẹ Orolu ko gbọdọ gbe igbesẹ kankan lori ọrọ yiyan ọba ilu naa titi ti wọn yoo fi yanju ẹjọ to wa ni kootu.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé Ọrẹ Òtítọ́jù Nítorí à…