Home ÀKỌ̀TUN Ọwọ́ tẹ Samuel tó ń díbọ́n títa omi tútù digunjalè
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - December 5, 2021

Ọwọ́ tẹ Samuel tó ń díbọ́n títa omi tútù digunjalè

Ọwọ́ tẹ Samuel tó ń díbọ́n títa omi tútù digunjalè

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ayé ti kásẹ̀ kan rọ̀ ó kù kan,ọ̀kan ọ̀hún ló tún ń mì dirodiro yìí o.
Ọmọọdún méjìdínlógún (18) ni Samuel Adetomi tọ́wọ́ àwọn agbófinró ikọ̀ ayára-bí-àṣá RRS (Rapid Response Squard) bà lọ́sẹ̀ tó kọjá yìí níbi tó ti ń ja àwọn onímọ́tò lólè lálẹ́, ọkùnrin náà sọ pé olè tòun kìí ṣe àkọsẹ̀bá tàbí e pé òun sèèsì débẹ̀, bàbá òun dira fóun pẹ̀lú òògùn abẹnugọ̀ǹògọ̀ kọ́un tó ó wá s’Ékòó ni, bọ́tú wọtà (bottle water) lòun máà ń tà lọ́sàn-án,olè háráńhún l’òùn l’óru.

Alaye ti CSP Ọlayinka Ẹgbẹyẹmi to jẹ ọga agba ikọ RRS ṣe l’Ọjọbọ, lori iṣẹlẹ ọhun ni pe ori biriiji Ọtẹdọla, lọna marosẹ Ojodu si Berger, nipinlẹ Eko, lawọn ti mu afurasi ọdaran naa lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun yii.

O ni mẹrin lawọn ọmọ ole tawọn ọlọpaa ri nibi ti wọn ti n fipa gba owo ati foonu lọwọ awọn onimọto ninu sun-kẹrẹ fa-kẹrẹ ọkọ to ṣẹlẹ lalẹ ọjọ naa, ṣugbọn bawọn ọlọpaa ṣe bẹ bọọlẹ ninu ọkọ wọn lati mu awọn afurasi ọdaran yii, niṣe lawọn naa bẹ danu bi wọn ṣe ri wọn, mẹta ninu wọn si sa lọ. Wọn ni ọkan tiẹ bẹ latori biriiji ọhun sinu ira nisalẹ.

Ṣugbọn orukọ ko ro Samuel ni tiẹ, Samuel o ribi sa, wọn mu un, wọn si fi pampẹ ofin gbe e. Ki wọn too mu oun naa, iṣẹ aṣelaagun ni wọn lawọn ọlọpaa ṣe, tori ọlọpaa bii mẹfa lo mu ọkunrin naa mọlẹ ki wọn too le fi ankọọfu si i lọwọ, lẹsẹ. Ọpọlọpọ igbo ati amuku igbo ni wọn ba lapo ẹ, pẹlu awọn oogun abẹnugọngọ oriṣiiriṣii.

Teṣan ọlọpaa ti wọn wọ ọ lọ lo ti jẹwọ pe oriṣiiriṣii gbẹrẹ ni baba oun ti sin sara oun, titi kan oruka toun wọ si atampako ẹsẹ osi oun.

O lọmọ bibi ilu Abeokuta loun, baba oun si ti se oun jinna koun too wa s’Ekoo lọdun to kọja. O lawọn oogun abẹnugọngọ naa lo maa n fun oun lagbara, toun fi le ṣe bii ọkunrin loju ija.

O loun o nile pato toun n gbe, ori biriiji ẹlẹsẹ loun maa n sun, adagun omi to wa labẹ biriiji naa loun si ti n wẹ. Iwọnba aṣọ polo meji toun ni loun fi n paarọ ara wọn, niṣe loun n fi owo toun ba ri nidii iṣẹ ole, jẹun.

Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, ti ni kawọn ọtẹlẹmuyẹ ni Panti tubọ ṣiṣẹ iwadii, ki wọn si mu awọn yooku to sa lọ. O lawọn maa foju wọn bale-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé Ọrẹ Òtítọ́jù Nítorí à…