Home ÀKỌ̀TUN Kò sí nǹkan tó ṣòro tó kí ènìyàn pàdánù ọkọ….. Bimbo Oshin
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - December 1, 2021

Kò sí nǹkan tó ṣòro tó kí ènìyàn pàdánù ọkọ….. Bimbo Oshin

Kò sí nǹkan tó ṣòro tó kí ènìyàn pàdánù ọkọ….. Bimbo Oshin

Ọrẹ Òtítọ́jù

Iná ọkọ,aya àti t’ọmọ,ọ̀kankan níbẹ̀ kò ní-ín jó wa.Àwọn tó sì sẹlẹ̀ sí ,Ọlọ́run à tù wọ́n lójú.
Ètò ìsìnkún gbajúgbajà oníṣòwò, tó tún jẹ́ ọkọ gbajúmọ̀ òṣèré tíátà Yorùbá, Bimbo Oshin, ìyẹn Ola Ibironke tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ si, Dúdú Heritage ti wáyé nílúù Ìbàdàn.

Ori papa ti wọn ti n gba ẹyin orilẹ ilẹ pẹlu igi sinu iho, Ibadan Golf Club ni eto naa ti kọkọ bẹrẹ.

Wọn bẹrẹ eto ọhun pẹlu gbingbin igi kan ni gbagede ti wọn ti n gba gọọfu naa lati ṣe iranti rẹ, ati lati ṣe apẹrẹ pe bo tilẹ jẹ pe o ti jade laye, yoo si wa laaye sibẹ.

Ọpọ awọn oṣere tiata Yoruba lo peju sibi eto isinku naa.

Lara awọn agba oṣere to wa nibẹ ni, Adewale Adeoye, ti ọpọ eeyan mọ mọ si Adewale Elesho ẹnu n ja waya.

Elesho sọ fun akọròyìn pe Dudu Heritage jẹ ẹnikan to lawọ gidi to si maa n fẹ ki itẹsiwaju ba ẹlomiran.
Bakan naa lo ni Dudu Hertiage kii ṣe ẹni to ni ahun, o si maa lawọ lati ṣe ore fun ọpọ eeyan.

Ẹwẹ, ọrẹ timọ-timọ si oloogbe ọhun, to tun jẹ mbalogun ẹgbẹ awọn to n gab gọọfu, amofin Idowu Salami sọ fun akọroyin pe ẹgbẹ awọn to n gba gọọfu naa n ṣedaro oloogbe.

O fi kun pe inu ọgba Ibadan Golf Club naa gangan ni Dudu wa nigba ti ọlọjọ de.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé Ọrẹ Òtítọ́jù Nítorí à…