Home ÀKỌ̀TUN Àwọn agbébọn tó jí tíṣà gbé ń bèèrè fún mílíọ̀nù mẹ́rin Náírà
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - November 28, 2021

Àwọn agbébọn tó jí tíṣà gbé ń bèèrè fún mílíọ̀nù mẹ́rin Náírà

Àwọn agbébọn tó jí tíṣà gbé ń bèèrè fún mílíọ̀nù mẹ́rin Náírà

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé wọ́n ní bí iná kò bá tán láṣọ, ẹ̀jẹ̀ kìí tán lórí èékáná.Ọ̀rọ̀ àwọn agbébọn wọ̀n yí ti di egbìrìn ọ̀tẹ̀ ,bí wọ́n tún ti nawón jà iṣẹ́ ibi wọn ji olùkọ́ àgbà kan, igbákejì rẹ̀ àtàwọn olùkọ́ méjì abẹ́ ẹ rẹ̀ gbé l’Ọ́jọ́bọ, tó kọjá yìí, la gbọ́ pé wọ́n ti ń bèèrè fún mílíọ̀nù mẹ́rin Náírà kí wọ́n tó lè tú wọn sílẹ̀ kúrò nínú ìgbékùn wọn.

Miliọnu marundinlogoji Naira lawọn ajinigbe naa kọkọ beere fun nigba ti wọn kan si awọn ẹbi wọn lọjọ Ẹti, Furaidee, lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ ni wọn lawọn janduku ọhun too gba ki ẹnikọọkan wọn san miliọnu kan Naira gẹgẹ bii owo itusilẹ wọn.

Ohun ta a gbọ ni pe ṣe lawọn ajinigbe naa kọ jalẹ lati ba Abilekọ Hellen Adeyẹmi to jẹ iyawo olukọ agba naa sọ ohunkohun, ohun ti wọn sọ fun un ni pe awọn ko fẹẹ ni nnkan i ṣe pẹlu obinrin, wọn lawọn ọkunrin nikan lawọn fẹẹ ba sọrọ.

Apapọ ẹgbẹ awọn olukọ agba ileewe girama nipinlẹ Ondo ti fi ẹdun ọkan wọn han lori bi awọn olukọ mẹrẹẹrin ṣe wa ninu igbekun awọn ajinigbe lati bíi ọjọ mẹta sẹyin lai ni ireti ọjọ ti wọn fẹẹ gba ominira.

Wọn ni ẹbẹ lawọn n bẹ awọn ajinigbe naa ki wọn siju aanu wo awọn ọmọ ẹni-ẹlẹni to wa ninu igbekun wọn, bakan naa ni wọn tun rọ ijọba lati gbe igbesẹ to yẹ lasiko.

Ọga agba fawọn ọlọpaa n’Ikarẹ Akoko, SP Akintujoye Akinwande, ni awọn ṣi n tẹsiwaju lati maa lepa awọn ọdaran ọhun ki wọn le ri awọn ti wọn ti ji gbe lọ naa gba pada lai fara pa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé Ọrẹ Òtítọ́jù Nítorí à…