Home ÀKỌ̀TUN A ò ní-ín bẹ Buhari torí i Sunday Igboho, torí kò dẹ́ṣẹ̀ kankan -Afẹ́nifẹ́re
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - November 28, 2021

A ò ní-ín bẹ Buhari torí i Sunday Igboho, torí kò dẹ́ṣẹ̀ kankan -Afẹ́nifẹ́re

A ò ní-ín bẹ Buhari torí i Sunday Igboho, torí kò dẹ́ṣẹ̀ kankan sí
Orílẹ̀-Afẹ́nifẹ́re

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re tó jà fún òmìnira Yorùbá, ti sọ pé àwọn ò ní-ín lọ̀ọ́ bá Ààrẹ Muhammadu Buhari sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ làwọn ò ní-ín ráwọ ẹ̀bẹ̀ kankan sí i pé kó lo agbára rẹ̀ láti tú Olóye Sunday Adeyẹmọ táwọn èèyàn mọ̀ sí Sunday Igboho sílẹ̀ láhàámọ́, torí kò sí ẹ̀sùn kan lọ́rùn ọkùnrin náà, kò sì sí ẹjọ́ kankan tó ń jẹ́ lọ́wọ́.

Akọwe ẹgbẹ Afẹnifẹre, Ọgbẹni Ṣọla Ebiseni, lo sọrọ yii lorukọ ẹgbẹ naa lọjọ Ẹti, ọsẹ yii, o ni, “ko si idi kankan tawọn Yoruba yoo fi lọọ bẹ ijọba apapọ lati tu Sunday Igboho silẹ. Lai ka bi ijọba Buhari ṣe n huwa ta-ni-maa-mu-mi si, a o ni i fara mọ iṣakoso ti ko bofin mu eyikeyii, ilana ofin nikan la fara mọ ni Naijiria.

Ṣebi ile-ẹjọ ti paṣẹ pe bijọba ṣe ṣakọlu sile Sunday Igboho lọganjọ oru lọjọsi, ti wọn fẹẹ pa a, ṣugbọn to jẹ awọn ẹmẹwa ẹ meji ni wọn pa, ti wọn si ba ọpọ dukia olowo iyebiye jẹ ko bofin mu, wọn lawọn tẹrọriisi ni wọn maa n ṣeru ẹ, wọn si ni kijọba san biliọnu lọna ogun Naira fun un gẹgẹ bii ẹtọ ẹ lori awọn nnkan ti wọn bajẹ.

Ṣe ijọba ti san an? Awọn ti wọn lọọ ya bo ile naa ki i ṣe agbofinro rara, wọn kan wọṣọ ijọba lasan ni, afẹmiṣofo ni wọn, tẹrọriisi gidi ni wọn.

Ṣebi ile-ẹjọ ti paṣẹ pe Sunday Igboho ko jẹbi kankan, wọn lọkunrin naa ko lẹjọ i jẹ, ijọba ni wọn da lẹbi, ti wọn si bu owo ti wọn gbọdọ san fun wọn.”

Ẹgbẹ Afẹnifẹre ni awọn nigbagbọ pe ododo ni yoo leke lori ahamọ ti wọn sọ Sunday Igboho si.

Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja ni Oluwoo ti ilẹ Iwo, Ọba AbdulRasheed Akanbi, gba awọn agbaagba Yoruba nimọran lati wo awokọṣe bawọn agbaagba ilẹ Ibo ṣe lọọ ba Buhari sọrọ lati tu Nnamdi Kanu to wa lahaamọ awọn ẹṣọ ọtẹlẹmuyẹ DSS, l’Abuja silẹ, latari ẹjọ to n jẹ lọwọ, ti Aarẹ si loun yoo ronu lori ẹbẹ wọn.

Ṣugbọn ẹgbẹ Afẹnifẹre lawọn o ni i ṣeru ẹ ni tawọn, tori Sunday Igboho ko dẹṣẹ kan ti wọn le tori ẹ fi i satimọle lorileede Olominira Bẹnẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé

Tinubu kí wọn nílé Akala l’Ogbomọṣọ, ò tún sàbẹ̀wò sí Gómìnà Mákindé Ọrẹ Òtítọ́jù Nítorí à…