Home ÀKỌ̀TUN Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - October 23, 2021

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn

Àwọn wọ̀nyí ti kékeré dèrò ẹ̀wọ̀n, jìbìtì orí ayélujára ló kó bá wọn

Ọrẹ Òtítọ́jù

Àwọn ló sọ pé, bí ọjọ́ gbogbo ṣe wù kó jẹ́ tolè tó, ọjọ́ kan á sá à jẹ́ ti olóhun.
Musiliu Sọdiq Dọlapọ gan- an lorúkọ rẹ̀,ṣùgbọ́n torí àti lu òyìnbó ní jìbìtì, ó sọ ara rẹ̀ di Wilson Janet, ó n jẹ́ orúkọ obìnrin. Ó ti rí òyìnbó lù ní jìbìtì kí àṣírí tó tú, ọgba bẹ́ẹ̀ ni sìnkún Àjọ EFCC tẹ̀ ẹ́ n’Íbàdàn, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n oṣù mẹ́sàn-án l’Ábẹ́òkúta.

Yatọ si Musiliu, ọmọkunrin kan naa wa t’oun pẹlu gba idajọ ẹwọn oṣu mẹsan-an l’Ọjọruu ti i ṣe ogunjọ, oṣu kẹwaa yii, orukọ tiẹ ni Ọlawuyi Ọlanrewaju Ridwan.

Ẹsun ti wọn ka sawọn mejeeji lẹsẹ nile-ẹjọ giga ilu Abẹokuta ni pe wọn fi ọgbọn jibiti gbowo lọwọ oyinbo lori ayelujara, wọn pe ara wọn lohun ti wọn ko jẹ, eyi si lodi sofin to de ihuwasi ẹni lori ayelujara.

Adajọ Joyce Abdulmalik, ti ile ẹjọ giga ilu Abẹokuta, lo gbọ ẹjọ naa. O paṣẹ pe kawọn ọmọde meji yii lọọ lo oṣu mẹsan-an mẹsan-an lẹwọn lai si aaye owo itanran, bẹẹ ni ki wọn da owo ti wọn fi jibiti gba naa pada.

Ni ti Musiliu, owo to din ni irinwo dọla (340 USD) ni Adajọ paṣẹ pe o gbọdọ da pada sọdọ ẹni to lu ni jibiti ọhun, bẹẹ ni ko si da foonu iphone 11 pro max kan to wa lọwọ ẹ pẹlu Itel kan pada funjọba Naijiria.

O paṣẹ pe ki Ọlawuyi da irinwo dọla (400USD) pada sapo ẹni toun naa lu ni jibiti. Bẹẹ naa ni yoo si tun da foonu iphone 11 to wa lọwọ tiẹ naa pada fun ijọba Naijiria, pẹlu ẹrọ gbohun-ghohun Bluetooth kan.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Kò sí nǹkan tó ṣòro tó kí ènìyàn pàdánù ọkọ….. Bimbo Oshin

Kò sí nǹkan tó ṣòro tó kí ènìyàn pàdánù ọkọ….. Bimbo Oshin Ọrẹ Òtítọ́jù Iná ọkọ,aya …