Home ÀKỌ̀TUN Àjọ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ “DSS”tú àwọn ọmọlẹ́yìn Sunday Igboho sílẹ̀ láhàámọ́,lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rìnléláàádọ́fà
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - October 23, 2021

Àjọ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ “DSS”tú àwọn ọmọlẹ́yìn Sunday Igboho sílẹ̀ láhàámọ́,lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rìnléláàádọ́fà

Àjọ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ “DSS”tú àwọn ọmọlẹ́yìn Sunday Igboho sílẹ̀ láhàámọ́,lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rìnléláàádọ́fà

Ọrẹ Òtítọ́jù

Àwọn àgbà bọ̀ ,wọ́n ní kò sí n tóle ko ko tí kìí rọ̀
Lẹ́yìn tí àwọn èèyàn náá ti lo oṣù mẹ́rin, ó dín ọjọ́ díẹ̀ látìmọ́lé iléeṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́, àwọn ọmọọṣẹ́ ajìjàgbara nnì, Sunday Adeyẹmọ tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn mọ̀ sí Sunday Igboho tí wọ́n fi pamọ́ sí àkàtà wọn latọjọ́ yìí síilẹ̀.

Ọjọ Eti opin ọsẹ yii ni wọn tu awọn eeyan naa silẹ lẹyin ti wọn lo ọjọ mẹrinlelaaadọfa (114) lakata wọn.

Awọn eeyan ti wọn pada tu silẹ ọhun ni obinrin kan to maa n kọ ọrọ sori ẹrọ ayelujara ti orukọ rẹ n jẹ Amudat Babatunde ti gbogbo eeyan mọ si Lady K ati Jamiu Oyetunji.

Ọjọ kin-in-ni, oṣu keje, ọdun yii, ni wọn ko awọn eeyan naa lasiko ti awọn ọtẹlẹmuyẹ naa ṣakọlu sile Sunday Igboho.

Bo tilẹ jẹ pe wọn pada gba beeli diẹ ninu wọn lẹyin ọpọlọpọ wahala latọdọ agbẹjọro wọn, sibẹ, wọn ko lati tu awọn meji yii silẹ, wọn ni wọn mọ nipa awọn nnkan ija oloro to wa nile Sunday Igboho.

Latigba naa ni Agbẹjọro wọn, Pẹlumi Ọlajẹngbesi, atawọn mi-in ti wa lori ọrọ naa, ko too di pe wọn gba itusilẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Kò sí nǹkan tó ṣòro tó kí ènìyàn pàdánù ọkọ….. Bimbo Oshin

Kò sí nǹkan tó ṣòro tó kí ènìyàn pàdánù ọkọ….. Bimbo Oshin Ọrẹ Òtítọ́jù Iná ọkọ,aya …