Home ÀKỌ̀TUN Nípìńlẹ̀ Kwara, àwọn aráàlú fẹ̀hónúhàn hàn torí owó iná ọba tó gbẹ́nu sókè,
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - October 22, 2021

Nípìńlẹ̀ Kwara, àwọn aráàlú fẹ̀hónúhàn hàn torí owó iná ọba tó gbẹ́nu sókè,

Nípìńlẹ̀ Kwara, àwọn aráàlú fẹ̀hónúhàn hàn torí owó iná ọba tó gbẹ́nu sókè,

Ọrẹ Òtítọ́jù

Látàrí bí iléeṣẹ́ tó ń pín iná ká (Ibadan Electricity), ṣe fowó kún owó iná oṣù Kẹwàá, nípìńlẹ̀ Kwara, àwọn oníbàárà nílùú Ilọrin, fẹ̀hónúhàn , wọ́n ní owó náà ti fẹ́ ẹ́ ju agbára àwọn lọ pẹ̀lú n tí ń lọ nílùú.

Niṣe ni awọn onibaara ọhun ya bo agbegbe Muritala, niluu Ilọrin, ti wọn si n pe fun ki wọn din owo naa ku tori pe ina ti wọn n mu wa ko yatọ si tatẹyinwa, ki waa lo mu ki owo gbẹnu soke si i. Awọn onibaara ọhun sọ pe iye ti wọn n san lowo ina losoosu ni naiara mejidinlaaadọta ati kọbọ mọkandinlogoji (N58.39k), ṣugbọn ni osu kẹwaa yii, o ti fo fẹrẹ si ọgọta naira ati naira mọkandinlogoji (60.39k), ti ina ọhun ko si fi bẹẹ duro ire. Iwadii fi han pe ni awọn ipinlẹ bii Ọsun, Ọyọ, Ogun, Ekiti ati bẹẹ bẹẹ lọ, ni ileesẹ apinaka IBEDC ti fi kun idiyele owo wọn.

Ọkan lara awọn onibaara to ba awọn oniroyin sọrọ lorukọ awọn ẹlẹgbẹ wọn, Arabinrin Aisat Bello, bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa pẹlu bi ileeṣẹ naa ṣe sadeede fi owo kun un lai fi to awọn onibaara leti tẹlẹ. Bello tẹsiwaju pe ileeṣẹ ọhun ko wo ipo ti eto ọrọ aje de duro bayii, wọn kan ṣa a fowo kun ina ni tiwọn ni. O wa pe fun iwadii to nipọn lori bi wọn ṣe fowo kun un lai sọ fun awọn onibara.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Kò sí nǹkan tó ṣòro tó kí ènìyàn pàdánù ọkọ….. Bimbo Oshin

Kò sí nǹkan tó ṣòro tó kí ènìyàn pàdánù ọkọ….. Bimbo Oshin Ọrẹ Òtítọ́jù Iná ọkọ,aya …