Home ÀKỌ̀TUN Ọkùnrin kan fìbínú yìnbọn fún’yàwó ẹ̀ n’Íbàdàn, ó ní kò tètè gbé ẹ̀rọ ìléwọ́ ẹ̀ nígbà t’óun pè é
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - October 17, 2021

Ọkùnrin kan fìbínú yìnbọn fún’yàwó ẹ̀ n’Íbàdàn, ó ní kò tètè gbé ẹ̀rọ ìléwọ́ ẹ̀ nígbà t’óun pè é

Ọkùnrin kan fìbínú yìnbọn fún’yàwó ẹ̀ n’Íbàdàn, ó ní kò tètè gbé ẹ̀rọ ìléwọ́ ẹ̀ nígbà t’óun pè é

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ẹni ṣe n tẹ́nìkan kò ṣe rí, àwọn àgbà ni ojú onítọ̀ún á rí n tẹ́nìkan kò rí ri. Àwárí t’óbìnrin n wá nnkan ọbẹ̀ làwọn ọlọ́dẹ àdúgbò àtàwọn agbófinró fi ọ̀rọ̀ ọ baálé ilé kan tí wọ́n porúkọ ẹ̀ ní Akeem Ọlaide, táwọn èèyàn mọ̀ sì “Àgbẹ̀dẹ,” ṣe, wọ́n sì ti fà á lé ọlọ́pàá téṣàn Orogun, nílúù Ìbàdàn, lọ́wọ́, látàrí bí wọ́n ṣe lọ́kùnrin náá fìbínú dáná ìbọn yá ìyàwó rẹ̀, ó ní kò tètè gbé aago rẹ̀ nígbà t’óun n pèé .

Iṣẹlẹ abaadi yii la gbọ pe o waye ni nnkan bii aago kan ọsan Ọjọbọ, nile kan to wa laduugbo Orogun, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.

Ọmọbinrin tọkọ-taya naa, Zainab, lo ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fawọn oniroyin, o ni ko pẹ ti mama oun ṣẹṣẹ ti ọja de, bo ṣe n ṣeto lati dana ounjẹ ọsan ni baba oun wọle pẹlu ibọn ibilẹ ponpo kan lọwọ rẹ, o lo faṣọ inuju, iyẹn ankaṣiifu kan bo ibọn naa.

Zainab ni “Bi wọn ṣe wọle ni wọn bẹrẹ si i ṣe gbolohun asọ pẹlu mama mi, ṣugbọn mo sọ fun mama mi pe ki wọn ma da wọn lohun mọ, tori mo ri i pe ija naa ti n di ariwo nla, mo tiẹ sọ fun wọn pe ki wọn sa lọ, tori emi ti ri nnkan kan to da bii ibọn lọwọ dadi mi, wọn fi aṣọ inuju bo o.

Mama mi o sa lọ, boya wọn ro pe Dadi mi o le yinbọn fawọn ni, nigba ti mo wọle lọọ bu omi, niṣe ni mo ṣadeede gbọ iro ibọn, ni mo ba sare jade, mo ba iya mi ti wọn n jẹrora iku nilẹ, ẹjẹ ti bo wọn, mo si ri baba mi ti wọn ba ọna ẹyinkule jade, wọn n sa lọ.”

Nigba ti wọn bi ọmọ naa leere pe ki lo fa ija awọn obi rẹ tọrọ fi di ranto, o ni koko kan ṣoṣo ti afurasi ọdaran naa tẹnu mọ ni pe iyawo oun ko tete gbe ipe rẹ boun ṣe n pe e leralera latoorọ, bẹẹ ni mama oun si fesi pe foonu oun ko si larọwọto oun nibi toun ti n ṣe ọrọ-aje lọwọ ni, ṣugbọn ọkunrin naa ko gba, o ni irọ lo n pa.

Wọn lọpẹlọpẹ awọn aladuugbo to sare de ibi iṣẹlẹ naa ni wọn gbe abilekọ to n joro ibọn naa lọ sọdọ oniṣegun ibilẹ kan to wa lagbegbe naa, Oloye Kẹhinde Ẹgẹ.

Oloye Ẹgẹ fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni ọta ibọn mọkanlelọgbọn lawọn ti fa yọ lara obinrin naa, ṣugbọn o ara rẹ ti n balẹ, awọn si ti n ṣeto lati gbe e lọ sọsibitu ijọba fun itọju iṣegun oyinbo.

Oluọde tilu Ajibọdẹ n’Ibadan, Oloye Sule Ọladimeji, naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o lawọn ọlọdẹ ti mu ọkunrin naa nibi to sa pamọ si, awọn ọlọpaa si ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun.

Ọmọ marun-un la gbọ pe obinrin tori ko yọ lọwọ iku ojiji yii bi fun ọkọ rẹ, ọmọbinrin mẹrin ati ọmọkunrin kan.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Kò sí nǹkan tó ṣòro tó kí ènìyàn pàdánù ọkọ….. Bimbo Oshin

Kò sí nǹkan tó ṣòro tó kí ènìyàn pàdánù ọkọ….. Bimbo Oshin Ọrẹ Òtítọ́jù Iná ọkọ,aya …