Home ÀKỌ̀TUN Olúbàdàn rọ ọ̀kan nínú àwọn Baálẹ̀ rẹ̀ lóyè
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 1 week ago

Olúbàdàn rọ ọ̀kan nínú àwọn Baálẹ̀ rẹ̀ lóyè

Olúbàdàn rọ ọ̀kan nínú àwọn Baálẹ̀ rẹ̀ lóyè

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé wọ́n ní n tí a kò bá
fẹ́ kó bàjẹ́, ó ní bí a tií ṣe
é, àti pé, olójú kò ní-ín yajú u rẹ̀ sílẹ̀,kó ní kó fọ́ èyí ló mú kí mú kí Olúbàdàn ilẹ̀ Ìbàdàn, Ọba Saliu Akanmu Adétúnjí, ó rọ ọ̀kan nínú àwọn baálẹ̀ tó wà lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀ lóyè, nítorí àwọn ìwà kòtọ́ tí ó n hù ,orúkọ onítọ̀ún ni Saidi Alatishe, Baálẹ̀ Lágelú Abọ̀kè, tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Ìdó, ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Gẹgẹ bi atẹjade ti Akọwe iroyin Olubadan, Adeọla Ọlọkọ, fi sita, o ni ọkunrin naa ti n luwẹẹ ninu wahala kan ati omi-in latigba to ti di baalẹ ninu oṣu kẹsan-an, ọdun 2017.

O fi kun un pe ọpo igba ni wọn ti n mu ẹsun baalẹ naa wa fun awọn iwa ko tọ to n hu kaakiri, eyi ti wọn lo lodi si aṣa ati ofin ilẹ Ibadan. Wọn ni laarin ọdun kan ti wọn fi n fi ẹsun kan ọkunrin yii, niṣe lo tun kọ lati waa sọ awijare tirẹ nigba ti wọn pe e pe ko waa ṣe bẹẹ. Eyi to jẹ iwa arifin si Olubadan ati awọn igbimọ rẹ.

Lara ẹsun to ni wọn fi kan an ni pe o pe ara rẹ ni ohun ti ko jẹ pẹlu bo ṣe fẹẹ fi awọn kan joye, nigba ti ko lẹtọọ lati ṣe bẹẹ nitori ki i ṣe ọmọ ọkunrin ninu idile naa.

Ninu lẹta ti awọn mọlẹbi Lagelu Abọke kọ si igbimọ Olubadan, eyi ti olori ẹbi wọn, Ganiyu Oladokun Okerinu Abọke, ati akọwe wọn kọ ni wọn ti sọ pe Saidi Alatiṣe to wa lati mọlẹbi Agbẹdẹ Adodo, n’Ibadan, ko le jẹ aṣoju fun mọlẹbi Lagelu Abọke ti Idi-Iṣhin, Bẹẹrẹ, niluu Ibadan.

Wọn ni yatọ si eleyii, awọn ko fọwọ si iwa ati iṣe rẹ, nitori iwa rẹ gẹgẹ bii baalẹ yatọ si awọn imọran ti wọn maa n fun awọn baalẹ ko too di pe wọn fi wọn joye baalẹ.

Eyi lo ni o fa a ti awọn igbimọ Olubadan fi fẹnu ko lati rọ ọkunrin naa loye. Irọloye yii si bẹrẹ loju-ẹsẹ ni.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…