Home ÀKỌ̀TUN Àwọn ọmọọ̀ta juná sí rélùwéèe tó n lọ sí Kano nílùú Ọffa
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 1 week ago

Àwọn ọmọọ̀ta juná sí rélùwéèe tó n lọ sí Kano nílùú Ọffa

Àwọn ọmọọ̀ta juná sí rélùwéèe tó n lọ sí Kano nílùú Ọffa

Ọrẹ Òtítọ́jù

Sé iná kò kúkú mojú ẹni
to dáa ,Ọjọ́rùú, ọṣẹ yii, ni ìbẹ̀rùbojo gbilẹ̀ ní ibùdokọ̀ ojú-irin ìlú Ọ̀ffà, ní ìpínlẹ Kwara, nígbà tí èrò kan tí wọn ò mọ̀ sọná sí ọkọ̀ ojú-irin tó kó èrò àti ẹrù tó n bọ̀ láti ìpínlẹ̀ Eko, tó n lọ sí ìpínlẹ̀ Kano.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ijọba ibilẹ Ọffa, niṣẹlẹ kayeefi naa ti waye, nigba ti wọn ni sadede ni ẹnikan ti wọn ko mọ, mọ-ọn-mọ juna si ọkọ oju-irin ọhun, to si fẹsẹ fẹ ẹ. Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe bi ina ṣe bẹrẹ si i jo lalaala lo ti na papabora.

Agbẹnusọ ajọ panapana nipinlẹ Kwara, Hakeem Adekunle, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ sọ pe ọpẹlọpẹ ileeṣẹ naa to tete gunlẹ sibi iṣẹlẹ ọhun ni ko jẹ ki ina ba nnkan jẹ kọja bo ṣe yẹ. Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni ọkọ ojú irin ọhun lo dẹnukọlẹ, ti wọn si n ṣe atunṣe rẹ lọwọ ni ẹnikan sadede ṣana si ọkọ naa, to si finu-fẹdọ ju ina si i, tawọn si pa ina naa to ku raurau, ṣugbọn ina ti mu abala meji ninu mẹwaa ninu ọkọ naa.

Adari agba ajọ naa nipinlẹ Kwara, Ọmọọba Falade John Olumuyiwa, ti waa rọ gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara lati maa pe ajọ panapana lasiko ti ina ba n sọṣẹ ni agbegbe wọn ki wọn le maa doola ẹmi ati dukia awọn olugbe ipinlẹ naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…