Home ÀKỌ̀TUN Àtúntò nìkan ló le è fòpin sí ìṣòro tí Nàìjíríà ń kojú lọ́wọ́- Gómìnà Akérédolú
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 2 weeks ago

Àtúntò nìkan ló le è fòpin sí ìṣòro tí Nàìjíríà ń kojú lọ́wọ́- Gómìnà Akérédolú

Àtúntò nìkan ló le è fòpin sí ìṣòro tí Nàìjíríà ń kojú lọ́wọ́- Gómìnà Akérédolú

Ọrẹ Òtítọ́jù
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní, bí a kò bá sáà mọ bi à n lọ, tá ò sì mọ bi a dé, ó sáà yẹ kí á mọ bi a ti pilẹ̀ ìrìnàjò. Bóyá èyí náà ló mú
Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó, Rótìmí Akérédolú, tó fi ní ṣíṣe àtúntò nìkan ló lè yanjú gbogbo ìṣòro táwọn ọmọ orílẹ̀-èdè yìí ń kojú lọ́wọ́lọ́wọ́.

Aketi fidi eyi mulẹ ninu ọrọ to bawọn eeyan ipinlẹ Ondo sọ lati fi sami ayajọ ominira to waye lọjọ Ẹti ọsẹ yii.

Akeredolu ni ko si ani-ani pe ọpọlọpọ aiṣedeedee lo wa ninu eto iṣejọba ti Naijiria n lo lọwọlọwọ, leyi to ṣokunfa bi gbogbo nnkan ṣe n ri rudurudu, ti iwa ọdaran si tun n fojoojumọ gbilẹ si i lawujọ.

O ni asiko yii gan-an lo yẹ kawọn ọmọ orilẹ-ede yii fimọ ṣọkan, kí wọn si jọ gbero lori ohun ti yoo jẹ ọna abayọ si gbogbo iṣoro ti awọn eeyan ilẹ yii n la kọja lọwọ.

Arakunrin ni ko sídìí to fi yẹ ki eyikeyii ninu awọn eeyan Naijiria jiya pẹlu ọpọlọpọ awọn nnkan alumọọni ti Ọlọrun fi ta ẹya kọọkan lọrẹ.

Akeredolu ni o ti to asiko to yẹ ki ijọba apapọ fun ipinlẹ kọọkan laaye ati maa ṣakoso awọn nnkan alumọọni to wa ni arọwọto wọn nitori pe awọn ajeji lasan ni wọn n ji awọn nnkan olowo iyebiye naa ko nibi tijọba tọju wọn si.

Bakan naa lo tun rọ ijọba apapọ pe ko fawọn gomina ipinlẹ kọọkan laaye lẹkun-un-rẹrẹ lati mojuto eto aabo agbegbe koowa wọn, ki nnkan le rọrun fawọn araalu.

Ni ipari ọrọ rẹ, Aketi pe awọn ọmọ ile igbimọ asofin ipinlẹ l’Abuja nija lati tun ijokoo wọn jo, ki wọn si wọna lati ṣatunṣe si ofin ọdun 1999, eyi to le jẹ ki ayipada rere tá a n fẹ tete ya kankan.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…