Home ÀKỌ̀TUN Ilé-ẹjọ́ Kòtẹ́mi-lọ́rùn bẹrẹ igbẹjọ lori ọrọ Sọtitobirẹ, wolii tọmọ pòórá n ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 3 weeks ago

Ilé-ẹjọ́ Kòtẹ́mi-lọ́rùn bẹrẹ igbẹjọ lori ọrọ Sọtitobirẹ, wolii tọmọ pòórá n ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀

Ilé-ẹjọ́ Kòtẹ́mi-lọ́rùn bẹrẹ igbẹjọ lori ọrọ Sọtitobirẹ, wolii tọmọ pòórá n ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ilé-ẹjọ́ ọ Kòtẹ́mi-lọ́rùn tó wà nílùú Akurẹ ti bẹ̀rẹ̀ ìjókòó lórí ẹjọ́ tí olùdásílẹ̀ ìjọ Sọtítóbirẹ̀ lágbàáyé, Wòlíì Alfa Samuel Babátúndé, pè ta ko ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n gbére tí wọ́n dá fún òun àtàwọn ọmọ ìjọ rẹ̀ márùn-ún lọ́dún tó kọjá.

Igbimọ olugbẹjọ ọhun, eyi ti Onidaajọ Rita Rosakhare Pemu jẹ alaga rẹ ni wọn pade lọjọ Aje,ọsẹ yii, lati gbọ awijare Wolii Alfa lori ẹsun ti wọn fi kan an pe o mọ nipa ọmọ ọdun kan, Gold Kọlawọle, to sọnu ninu sọọsi rẹ lọjọ kẹwaa, oṣu kọkanla, ọdun 2019.

Wolii Alfa ninu awijare rẹ rọ igbimọ olugbẹjọ naa lati fagi le idajọ ẹwọn gbere ti wọn da fun oun atawọn marun-un mi-in nitori pe iya ẹṣẹ aimọdi lawọn n jẹ lọwọ.

Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ lẹyin ọpọlọpọ ariyanjiyan lati ọdọ agbẹjọro awọn olupẹjọ ati tijọba, alaga igbimọ, Onidaajọ Rita, ni oun yoo kan sawọn tọrọ kan laipẹ lori ọjọ ti awọn ba fẹnu ko si fun idajọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…