Home ÀKỌ̀TUN Àwọn ọmọ ‘Yahoo’ ju òkú ọmọbìnrin kan sí ẹ̀bá a ṣọ́ọ̀òsì l’Akurẹ
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 3 weeks ago

Àwọn ọmọ ‘Yahoo’ ju òkú ọmọbìnrin kan sí ẹ̀bá a ṣọ́ọ̀òsì l’Akurẹ

Àwọn ọmọ ‘Yahoo’ ju òkú ọmọbìnrin kan sí ẹ̀bá a ṣọ́ọ̀òsì l’Akurẹ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àdúrà kí á má ràrìnrá ni a máa n gbà, ṣùgbọ́n kò jọ pé àdúrà yìígbà fún ọmọbìnrin kan bí ṣe bá òkú u rẹ̀ pàdé lẹ́gbẹ̀ẹ́ ṣọ́ọ̀sì nlá kan tó wà lágbègbe Oke-Ijẹbu, nílùú Akurẹ, láàárọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọ̀sẹ̀ yìí.

Ókú ọmọbìnrin ọ̀hun tí kò sẹ́ni tó tí ì mọ ibi tó ti wá ni wọ́n fi aṣọ funfun wé, tí wọ́n sì tún kó àwọn nnkan mí-ìn sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ nítòsí ojú títí tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.

Ọ̀kan nínú àwọn tó wà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún sọ pé kò sẹ́ni tó lè sọ pàtó àsìkò tí wọ́n gbé òkú ọmọbìnrin ọ̀hún wá sí agbègbè náà.

Ó ní àkíyèsí tí àwọn ṣe ni pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ọmọ Yahoo kan ni wọ́n lò ó, tí wọ́n sì fi òru bojú ju òkú rẹ̀ sí agbègbè táwọn èèyàn ti bá a nígbà tí ilẹ̀ mọ́.

Òkú ọ̀hun sì wà níbẹ̀ tí kò sẹ́ni tó tí i fọwọ́ kàn án.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run

Ìyá Rainbow ṣọjóòbí, ó ní ẹ̀bẹ̀ pàtàkì kan lòun n bẹ Ọlọ́run Ọrẹ Òtítọ́jù Ayẹyẹ ọjọ́ọ̀bì à…