Home ÀKỌ̀TUN IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 2 weeks ago

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀fọ́n àn tọ̀ sí gbẹ̀gìrì, oníkálùkù ti fẹ́ kó ẹ̀kọ rẹ̀ dání lọ̀rọ̀ dà báyìí bí ẹgbẹ́ ajìjàgbara IPOB tó n pè fún ìdásílẹ̀ orílẹ̀-èdè Biafra ti tako ìgbésẹ̀ Ààrẹ Muhammadu Buhari láti ṣe àbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ Imo lọ́sẹ̀ yìí. Wọ́n ní àwọn kò fẹ́ rí Ààrẹ ní regbéregbé ẹkùn ìlà oòrùn Gúúsù Nàìjíríà lọ́wọ́ yìí.

Adarí ètò fún ẹgbẹ́ IPOB, Chika Edoziem ló kéde ọ̀rọ̀ yìí.

Ọgbẹni Chika wa pàṣẹ ofin kóńlé-ó-gbélé lati tako àbẹwò Buhari sí ipinlẹ Imo ni l’Ojobo.

“A ò fẹ́ Buhari ní ìpínlẹ̀ Imo nílẹ̀ Biafra ní ọjọ́ kẹsàn án oṣù kẹsàn án yìí”

Bákan náà ni ẹgbẹ́ náà tún fọnrere rẹ̀ pé kí gbogbo àwọn ọbaalayé àtàwọn ọ̀tọ̀ọ̀kùlú ó jìnà síbi àbẹ̀wò náà paàpá ètò yòówù tí gómìnà ipinlẹ Imo, Hope Uzodinma bá gbé kalẹ̀ nítorí Ààrẹ Buhari.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Imo, Uzodimma ti kéde èròngbà Buhari tẹ́lẹ̀ láti ṣe àbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ náà.

Uzodimma tó kéde àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ náà ṣàlàyé pé ọ̀kan ò jọ̀kan àkànṣe iṣẹ́ ni Ààrẹ yóó ṣí lásìkò àbẹ̀wò rẹ̀ ọ̀hún.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn ológun ní orílẹ̀-èdè Guinea gbàjọba nílẹ̀ ọ̀hún

Àwọn ológun ní orílẹ̀-èdè Guinea gbàjọba nílẹ̀ ọ̀hún. Ọrẹ Òtítọ́jù Ìdìtẹ̀gbàjọba ti wó ìjọ…