Home ÀKỌ̀TUN Olúwòó fẹ́ ṣe ayẹyẹ ‘Ọdún Ọlọ́run’
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 2 weeks ago

Olúwòó fẹ́ ṣe ayẹyẹ ‘Ọdún Ọlọ́run’

Olúwòó fẹ́ ṣe ayẹyẹ ‘Ọdún Ọlọ́run’

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ará kìí tán nílé alárà sáà ni ọ̀rọ̀ Kábíyèysí Olúwòó yìí bó ṣe jẹ́ pé ojúmọ̀ kan àrà kan ni ti ẹ̀ , Kábíyèysí ní òun ń
fi ìmọrírì hàn sí iṣẹ́ agbára Ọlọ́run, òun gẹ́gẹ́ bí Olúwòó ti ìlú Ìwó, Ọba Abdulrosheed Adéwálé Àkànbí, ti kéde ọjọ́ kẹsàn- án, oṣù Kọkànlá, ọdún yìí, gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ ti òun yà sọ́tọ̀ láti ṣe ayẹyẹ “Ọdun Ọlọrun”.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin rẹ, Alli Ibaheem, fi sita lo ti sọ pe iyin si Ọlọrun nikan ni wọn yoo fi ọjọ naa ṣe.

O ni ayẹyẹ naa yoo jẹ ipejọpọ gbogbo awọn eeyan lai fi ti ẹsin tabi ẹya ṣe rara, bi ko ṣe lati fi imọriri Ọlọrun han fun aabo, aanu, ipese, itọni ati agbara rẹ lai ka gbogbo laasigbo to n doju kọ aye lọwọlọwọ ṣi.

Alli ṣalaye pe bi Musulumi ṣe n ṣayẹyẹ ọdun itunu aawẹ ati Ileya, ti awọn Kristiẹni naa si n ṣe ọdun Keresimesi, naa ni Oluwoo, gẹgẹ bii baba fun gbogbo awọn aṣaaju, ti ko si si ninu ẹgbẹ okunkun, ṣe ṣagbekalẹ eto naa.

Gẹgẹ bo ṣe wi, o tọ lati fi imọriri han si Ọlọrun to da eniyan latinu erupẹ, to si fun wọn lagbara lati jọba lori ohun gbogbo to ku to da, to si tun lagbara lati pa ọkan ati ẹmi mọ.

O ni ko si nnkan miiran ti wọn yoo ṣe lọjọ naa ju iyin ati ọpẹ si Ọlọrun lọ nitori Oun nikan ni gbogbo ọpẹ tọ si

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo Fẹ́mi Akínṣọlá Ọ̀fọ́n àn tọ̀ sí gbẹ̀gìr…