Home ÀKỌ̀TUN Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò jí bàbá a wọn gbé, wọ́n ń bèèrè owó ìdáǹdè
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 2 weeks ago

Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò jí bàbá a wọn gbé, wọ́n ń bèèrè owó ìdáǹdè

Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò jí bàbá a wọn gbé, wọ́n ń bèèrè owó ìdáǹdè

Ọ̀rẹ Òtítọ́jù

Yórùbá bọ̀, wọ́n ní ojú ẹni la tií mọ àkúùsin ẹni.
Ìyá àti bàbá kan ló bí àwọn ọkùnrin méjì kan, ní Yola, ní ìpínlẹ̀ Adamawa. Ṣùgbọ́n níṣe làwọn méjèèjì ọ̀ún tẹ̀gbọ́n-tàbúrò yìí gbìmọ̀-pọ̀, tí wọ́n jí bàbá tó bí wọn gbé, wọ́n sì ti ń bèèrè owó ìtúsílẹ̀ paàpá, kó tó ó di pé ọwọ́ ọ pálábá wọ́n ṣégi.

Ohun to ṣẹlẹ gẹgẹ ba a ṣe gbọ ni pe lẹyin ti awọn gende meji ọhun ji baba wọn gbe tan, wọn tọju rẹ sibi ti ẹnikẹni ko ti ni i fura. Lẹyin igba naa ni wọn si waa n beere owo rẹpẹtẹ lọwọ awọn ẹgbọn ati aburo baba naa, wọn ni bi wọn ko ba mu owo wa, ki wọn gbagbe pe wọn yoo tun foju kan eeyan wọn naa mọ o.

Ṣugbọn awọn ẹbi baba wọn ko ri owo tawọn ajinigbe naa n beere san, ko si jọ pe kinni kan wa ti wọn le ṣe si i rara.

Nigba tawọn mejeeji yii ko ri owo gba, ti wọn ko si fẹ ki aṣiri tu pe awọn lawọn ji baba awọn gbe, wọn pinnu lati kuku pa a danu, ki ohun to n run nilẹ tan kia.

Afi ti pe awodi oke wọn ko mọ pe ara ilẹ n wo oun, awọn ọmọ to ji baba gbe yii ko mọ pe ẹni kan ri awọn lasiko ti wọn n gídì baba naa mọlẹ, ti wọn fipa wọ ọ sinu ọkọ ti wọn fi gbe e lọ.

Ẹni naa lo ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fawọn ẹbi baba naa to n daamu lati san owo itusilẹ rẹ, bi wọn ṣe lọọ fọlọpaa gbe awọn ọmọ yii niyẹn.

Awọn mejeeji ti wa latimọle bayii, ko le pẹ ti wọn yoo fi de kootu, lati dahun ẹsun ijinigbe.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo Fẹ́mi Akínṣọlá Ọ̀fọ́n àn tọ̀ sí gbẹ̀gìr…