Home ÀKỌ̀TUN Atiku Abubakar ń gbìyànjú àti pẹ̀tù sááwọ̀ láàrin Gómìnà Ṣèyí Mákindé àti igun PDP kan l’Ọ́yọ̀
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 2 weeks ago

Atiku Abubakar ń gbìyànjú àti pẹ̀tù sááwọ̀ láàrin Gómìnà Ṣèyí Mákindé àti igun PDP kan l’Ọ́yọ̀

Atiku Abubakar ń gbìyànjú àti pẹ̀tù sááwọ̀ láàrin Gómìnà Ṣèyí Mákindé àti igun PDP kan l’Ọ́yọ̀

Ọ̀rẹ Òtítọ́jù

Ṣé àwọn àgbà ní n tí a kò bá fẹ́ kó bàjẹ́, ó ní bí a tií ṣe é. Bẹ́ẹ̀ àgbà gidi kò níín wà lọ́jà, kórí ọmọ ìkókó ó wọ́ lẹ́yìn ìyá ẹ̀.
Olùdíje sípò o Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP, Atiku Abubakar ti dá sí aáwọ̀ tó jẹyọ láàrin Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Ṣèyí Mákindé àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀hún tó ń fi apá jánú.

Abubakar Atiku lo gbe igbesẹ naa lasiko to wa si ilu Ibadan lati si papakọ iṣere, Lekan Salami Sports Complex in Adamasingba, ni ilu Ibadan.

Awọn oloṣelu miran to wa nibi ipade naa ni gomina ipinlẹ Niger, Aliyu Babangida, Sẹnato Abiodun Olujimi, Dino Melaye ati awọn miran.

Awọn igun kan ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ni ko faramọ bi gomina Makinde ṣe n dari ẹgbẹ naa ni ipinlẹ Ọyọ, ti wọn si pinnu lati ṣiṣẹ tako gomina naa.

Awọn igun naa ni awọn ti lọ gba fọọmu ti wọn yoo fi dibo fun ẹlomiran tako awọn ti gomina Makinde yan lati dije dupo labẹle fun ipo si awọn adari ẹgbẹ naa ni ipinlẹ.

Nibi ipade naa ni awọn aṣoju igun to n binu naa bi Oloye Nureni Akanbi, Alhaji Hazeem Gbolarumi, Alhaji Bola Akinyemi ti fi aidunnu wọn han si gomina Seyi Makinde.

Amọ Atiku lo rawọ ẹbẹ si wọn lati maṣe gbe iru igbesẹ bẹẹ, pẹlu idaniloju pe gbogbo ẹdun ọkan wọn ni oun yoo yanju ni pẹlẹ-putu.

Bakan naa lo fi da wọn loju wi pe ipade alaafia miran yoo waye laarin awọn igun to n fi apa janu naa ati gomina Makinde.

Ninu ọrọ awọn ti inu wọn ko dun si iṣejọba Gomina ni wọn ti sọ wi pe, gbogbo igba ni ipade n waye lai si aṣeyọri.

Wọn ni ipade ti awọn ṣe pẹlu sẹnetọ Bukola Saraki ni wọn ti pinnu lati gba alaafia laaye, ti gomina naa si parọwa si wọn pe ki ipari Osu Kẹjọ to de ni atunṣe yoo waye.

Amọ wọn ni titi di asiko yii, ko i tii si aṣeyọri kankan nipa gbogbo ọrọ ti awọn to wa nibi ipade naa panupọ sọ wi pe yoo jẹ ọna abayọ si idojukọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Oyo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo Fẹ́mi Akínṣọlá Ọ̀fọ́n àn tọ̀ sí gbẹ̀gìr…