Home ÀKỌ̀TUN Àwọn agbébọn jí ọmọléèwé rẹpẹtẹ gbé lọ́sàn-án gangan ní ìpínlẹ̀ Zamfara
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 2 weeks ago

Àwọn agbébọn jí ọmọléèwé rẹpẹtẹ gbé lọ́sàn-án gangan ní ìpínlẹ̀ Zamfara

Àwọn agbébọn jí ọmọléèwé rẹpẹtẹ gbé lọ́sàn-án gangan ní ìpínlẹ̀ Zamfara

Ọ̀rẹ Òtítọ́jù

Kàkà kó dẹ̀ lára ewé àgbọn, ko ko ko ló ń le síi lọ̀rọ̀ àwọn jàǹdùkú agbébọn tó ń ṣoro bí agbọ́n lápá Òkè-Ọya ilẹ̀ wa báyìí, àyà ti kò wọ́n débii pé wọn ò fòru bojú gbé sùnmọ̀mí mọ́,ọ̀sán gangan ni wọ́n ń lọ̀ọ́ jí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ rẹpẹtẹ kó nílùú Kaya, tí í ṣe ìlú abínibí gómìnà ìpínlẹ̀ Zamfara.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, nnkan bii aago mejila kọja iṣẹju diẹ lọsan-an Ọjọru yii, lawọn agbebọn ti wọn pọ rẹpẹtẹ gun ọkada wọ ilu Kaya, taara ni wọn fori le ileẹkọ girama ijọba, Government Day Secondary School, to wa nijọba ibilẹ Maradun, nipinlẹ Zamfara, wọn nileẹkọ naa ko jinna si agboole ti wọn bi Gomina Bello Matawale si, to ti ṣe kekere rẹ. Wọn yinbọn ni koṣẹ-koṣẹ, lawọn aladuugbo ba bẹrẹ si i sa asala fẹmii wọn, bẹẹ lawọn agbebọn naa bẹrẹ si i ko awọn ọmọọleẹkọ ti wọn n kawe lọwọ ni kilaasi wọn sori awọn ọkada ti wọn gbe wa, wọn si ko eyi to pọ ju lọ lara wọn wọgbo lọ.

Oṣiṣẹ ọfiisi gomina ọhun ti ko fẹẹ sọ orukọ ara rẹ fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni ko ti i sẹni to mọ iye awọn ọmọleẹkọ tawọn agbebọn naa ji gbe wọgbo, ṣugbọn Gomina Matawale ti gbọ si iṣẹlẹ yii.

“Loootọ niṣẹlẹ yii waye, o baayan ninu jẹ pe titi tawọn agbebọn naa fi pari iṣẹ buruku wọn, ko sẹni to le yẹ wọn lọwọ wo.

Gomina ati awọn lọgalọgaa lẹka eto aabo ti n ṣepade lori ọrọ yii, ireti wa pe wọn yoo fi atẹjade lede lori rẹ laipẹ, wọn yoo si sapa lati doola ẹmi awọn majeṣin ọhun,” gẹgẹ bo ṣe wi.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo Fẹ́mi Akínṣọlá Ọ̀fọ́n àn tọ̀ sí gbẹ̀gìr…