Home ÀKỌ̀TUN Mínísítà méjì níjọba Buhari pàdànù ipò o wọn
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 3 weeks ago

Mínísítà méjì níjọba Buhari pàdànù ipò o wọn

Mínísítà méjì níjọba Buhari pàdànù ipò o wọn

Ọ̀rẹ Òtítọ́jù

Ṣé wọ́n ní bí ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọmọ ẹranko kò bàjẹ́, tọmọ èèyàn kò lè gbénú ìkòkò ọbẹ̀ ṣe yùngbàyùngbà.

Méjì lára àwọn mínísítà tó ń bá ìjọba àpapọ̀ ṣiṣẹ́,Mínísítà fétò ọ̀gbìn, Alaaji Mohammed Sabo Nanono, àti Mínísítà lórí ọ̀rọ̀ agbára, Alaaji Mamman Saleh, ti pàdánù ipò o wọn, Ààrẹ Muhammadu Buhari ti gbaṣẹ́ lọ́wọ́ ọ wọn, lẹ́yẹ ò sọkà ló sì ti yan àwọn méjì mí-ìn rọ́pò o wọn.

Oludamọran pataki fun Aarẹ lori eto iroyin ati ipolongo, Ọgbẹni Fẹmi Adeṣina, lo kede ọrọ yii lọsan-an Ọjọruu, l’Abuja, ninu atẹjade kan.

Fẹmi Adeṣina tun kede pe Aarẹ Buhari ti yan Minisita lori ọrọ ayika tẹlẹ, Mohammed Mahmoud Abubakar, lati di minisita feto ọgbin, bakan naa ni wọn gbe minisita agba ni ileeṣẹ ode ati ile gbigbe, Abubakar Aliyu, lọ si ileeṣẹ agbara gẹgẹ bii minisita bayii.

Atẹjade naa ko sọ idi pato ti Aarẹ fi ṣe ipinnu yii.

Adeṣina ni Buhari dupẹ lọwọ awọn mejeeji, o si ṣadura ki wọn ṣoriire ninu ohun yoowu ti wọn ba dawọ le bi wọn ṣe n pada sile wọn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo Fẹ́mi Akínṣọlá Ọ̀fọ́n àn tọ̀ sí gbẹ̀gìr…