Home ÀKỌ̀TUN Fífi màálù jẹko dèèwọ̀ poo ní ìpínlẹ̀ Ondo, Akeredolu buwọ́ lùwé òfin
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 3 weeks ago

Fífi màálù jẹko dèèwọ̀ poo ní ìpínlẹ̀ Ondo, Akeredolu buwọ́ lùwé òfin

Fífi màálù jẹko dèèwọ̀ poo ní ìpínlẹ̀ Ondo, Akeredolu buwọ́ lùwé òfin

Ọ̀rẹ Òtítọ́jù

Ṣé wọ́n ní ìlú tí kò sófin, ẹ̀ṣẹ̀ kò sí níbẹ̀.

Àfi ẹni tó baọ́á fẹ́ẹ́ fọwọ́ pa idà òfin lójú ló lè fi màálù jẹko ní gbangba lásìkò yìí ní ìpinlẹ Òǹdó àti ìgbèríko rẹ̀, pẹ̀lú bí Gómìnà Oluwarotimi Akeredolu ṣe buwọ́ lu àbádòfin tó sọ àṣà ọ̀hún dèèwọ̀, tó sì ti di òfin ní ìpínlẹ̀ Òǹdó.

Atẹjade kan ti kọmiṣanna feto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ Ondo fi lede lori ọrọ yii lọjọ Iṣẹgun, sọ pe Akeredolu gbe igbesẹ yii ni ibamu pẹlu ipinnu tawọn gomina iha Guusu ilẹ wa fẹnuko le lori ninu ipade ti wọn ṣe kẹyin.

Ninu ipade naa, eyi to waye nileejọba ipinlẹ Eko, l’Alausa, Ikẹja, ni wọn ti gbe gbedeke kalẹ pe gbogbo ipinlẹ mẹtadinlogun to ṣepade naa gbọdọ fidi ofin to ta ko fifi maaluu jẹko ni gbangba mulẹ ni ipinlẹ kaluku wọn ko too di ọjọ ki-in-ni, oṣu kẹsan-an, ọdun yii.

“Igbesẹ yii ṣe pataki, o ṣe koko, lati fopin si iṣoro ati aawọ to n figba gbogbo waye lori ọrọ fifi ẹran jẹko ni gbangba, ki awọn eeyan ipinlẹ Ondo le fi ẹdọ wọn leri oronro.

“A o ṣe ofin yii lati doju sọ ẹya tabi awujọ eeyan kankan, bẹẹ la o ṣe e lati finran, a ṣe e lati mu ki ajọṣepọ, anfaani tọtun-un tosi, laarin awọn olugbe ipinlẹ Ondo tubọ rẹsẹ walẹ ni, lai ka ẹya tabi ẹsin tabi ede ti ẹnikẹni n sọ si.

“A reti pe kawọn olugbe ipinlẹ Ondo pa ofin yii mọ, tori ilu ti ko ba si ofin lẹṣẹ ko si, ijọba ko ni i fojuure wo ẹnikẹni to ba tasẹ agẹrẹ si ofin naa, onitọhun yoo kan dudu inu ẹkọ nile-ẹjọ.

Latari eyi, ijọba yoo sapa lati jẹ kawọn eeyan mọ hulẹhulẹ ofin yii, ko si wa larọwọto wọn nibikibi ti wọn ba wa, tori ko si awawi kan to maa ṣetẹwọgba lori ofin ọhun.”

Bi atẹjade naa se sọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo Fẹ́mi Akínṣọlá Ọ̀fọ́n àn tọ̀ sí gbẹ̀gìr…