Home ÀKỌ̀TUN Ọwọ́ tẹ tíṣà tó ń fipá bá ọmọ tó bi nínú ara ẹ̀ lò pọ̀ l’Óǹdó
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 3 weeks ago

Ọwọ́ tẹ tíṣà tó ń fipá bá ọmọ tó bi nínú ara ẹ̀ lò pọ̀ l’Óǹdó

Ọwọ́ tẹ tíṣà tó ń fipá bá ọmọ tó bi nínú ara ẹ̀ lò pọ̀ l’Óǹdó

Ọrẹ Òtítọ́jù

Òpin ayé ń kànkùn gbọ̀ngbọ̀n náà ló ṣe jẹ́ pé ọ̀pọ̀ n tó sàjèjì sétí nígbàkan rí ti wá di bárakú báyìí lóde òní.

Olùkọ́ iléẹ̀kọ́ girama kan, Nelson Akinṣọwọn, lọwọ́ ti tẹ̀ lórí ẹ̀sùn fífipá bá ọmọ bíbí inú rẹ̀ lò pọ̀ nílùú Òǹdó, níjọba ìbílẹ̀ Ìwọ̀-Oòrùn Òǹdó.

Ohun ta a gbọ ni pe lati igba ti ọmọbinrin naa ti wa lẹni ọdun mẹwaa lo ti n foju wina ibalopọ baba rẹ, kinni ọhun ko si figba kankan dawọ duro titi to fi di bii ọmọ ọdun mẹtadinlogun ti aṣiri ọrọ yii pada tu sita.

Ninu alaye ti ọmọbinrin ta a forukọ bo laṣiiri ọhun ṣe fawọn oniroyin kan to fọrọ wa wọn lẹnu wo, o ni ni nnkan bii ọdun meje sẹyin ni ija nla kan waye laarin awọn obi oun, leyii to ṣokunfa bawọn mejeeji ṣe kọ ara wọn silẹ gẹgẹ bii ọkọ ati aya.

O ni ko pẹ rara ti iya oun kẹru jade tan ni baba oun ti bẹrẹ si i ba oun lo pọ pẹlu ipa, eyi lo ni o saaba maa n waye nigbakuugba ti ọkunrin to n ṣiṣẹ tiṣa naa ba ti mu ọti yo.

O ni bo tilẹ jẹ pe ọpọ igba ni iyawo baba oun ti awọn jọ n gbe maa n gba oun nimọran lati yago fun iṣekuṣe, sibẹ ẹru biba ki i jẹ ki oun le sọ ohunkohun jade lori iṣẹlẹ.

Nigba tọrọ yii su oun loun sa kuro nile, ti oun si lọọ farapamọ sibi kan titi digba tawọn ọlọpaa tesan Fagun, niluu Ondo, fi ranṣẹ si i pe ko yọju sawọn.

Ṣe ni Nelson ṣẹ kanlẹ lori ẹsun ti ọmọ rẹ fi kan an to ni irọ patapata ni, o ni o da oun loju pe iyawo oun to jẹ iya ọmọ naa lo n ti i ni itikuti lati waa parọ mọ oun ni tesan.

Alukoro ileesẹ ipinlẹ Ondo, Funmi Ọdunlami, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni iwadii ṣi n tẹsiwaju, bo tilẹ jẹ pe afurasi ẹni ọdun marundinlaaadọta ọhun si n ṣẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo Fẹ́mi Akínṣọlá Ọ̀fọ́n àn tọ̀ sí gbẹ̀gìr…