Home ÀKỌ̀TUN Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, Nàìjìríà yìí kò ní ín pín–Ọbasanjọ
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 3 weeks ago

Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, Nàìjìríà yìí kò ní ín pín–Ọbasanjọ

Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, Nàìjìríà yìí kò ní ín pín–Ọbasanjọ

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé n tí ó kọjú séèyàn kan, ó ṣeéṣe kó kọ̀yìn sí ẹlòmíràn.
Kò sí àníàní,Olóyè Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ kò fìgbà kan wà lẹ́yìn àwọn tó ǹ pè fún ìpínyà Nàìjìríà. Ṣùgbọ́n lọ́jọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹjọ yìí, ló tún wá bó o lójú tán, Ààrẹ tẹ́lẹ̀ ọ̀hún sọ pé ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, Nàìjìríà kò ní-ín túká, yóó wà níkan ṣoṣo lọ ni.

Ilu Eko l’Ọbasanjọ ti sọrọ yii, lasiko to lọọ ba Ojiṣẹ Oluwa, Sunday Mbang, yọ ayọ ọjọọbi ọdun karundinlaaadọrun-un (85), ati ifilọlẹ iwe kan to sọ itan igbesi aye baba naa.

Nigba to n ṣalaye, Ọbasanjọ sọ pe awọn kan wa ti wọn jẹ ọta Naijiria, o ni wọn pọ, ṣugbọn wọn ko ni i ri kinni naa ṣe pe ki Naijiria tuka. O ni wọn yoo ṣubu ni.

Ọbasanjọ sọ pe bi Naijiria ba wa lodidi bo ṣe wa yii, o pe wa pupọ, nitori ohun ti a maa koju papọ gẹgẹ bii iran eniyan rọrun, o si tura ju ka tuka yẹlẹyẹlẹ lọ.

O loun gẹgẹ bii ẹnikan, iṣọkan orilẹ-ede yii loun yoo maa ṣiṣẹ fun. O ni labẹ bo ṣe wu ko ri, ati ohun yoowu ko ṣẹlẹ, Naijiria yii ko ni i pin, awọn to jẹ ọrẹ Naijiria ni yoo bori, awọn ọta rẹ yoo ṣubu ni.

Ẹ oo ranti pe awọn ajijagbara ti wọn n beere Orilẹ-ede Oduduwa ko duro, bẹẹ lawọn Ibo ti wọn n beere Biafra naa ko sinmi. Ṣugbọn Ọbasanjọ ni oun gẹgẹ bii ẹnikan ko ni i fara mọ ipinya, oun ko ni i ba awọn to fẹẹ tu Naijiria ka ṣe ni toun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo Fẹ́mi Akínṣọlá Ọ̀fọ́n àn tọ̀ sí gbẹ̀gìr…