Home ÀKỌ̀TUN Ẹ fi Sunday Igboho lọ́rùn sílẹ̀ o, ẹ jẹ́ kó máa bá ìrìnàjò ẹ̀ lọ —Soyinka
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 3 weeks ago

Ẹ fi Sunday Igboho lọ́rùn sílẹ̀ o, ẹ jẹ́ kó máa bá ìrìnàjò ẹ̀ lọ —Soyinka

Ẹ fi Sunday Igboho lọ́rùn sílẹ̀ o, ẹ jẹ́ kó máa bá ìrìnàjò ẹ̀ lọ —Soyinka

Ọrẹ Òtítọ́jù

Àwọ́n àgbà ní ọmọ ẹni kò ṣèdí bẹ̀bẹ̀rẹ̀, ká kó ìlẹ̀kẹ̀ sí ìdí ọmọ ẹlòmíràn.
Ògbóǹtarìgì òǹkọ̀tàn àti ọmọwe nnì, Ọ̀jọ̀gbọ́n Wọlé Ṣóyínká, ti pàrọwà síjọba orílẹ̀ èdè Olómìnira Benin pé kí wọ́n tú èékánná lẹ́yìn ọrùn gbajúgbajù ajìjàgbara ilẹ̀ Yorùbá, Olóyè Sunday Adéyẹmọ, táwọn èèyàn mọ̀ sí Sunday Igboho, tó ti wà láhàámọ́ wọn.
Ṣoyinka lóun ò rí ẹ̀sùn tàbí ẹ̀ṣẹ̀ pàtó kan tí wọ́n mú ọkùnrin ọ̀hún sáhàámọ́ fún.
Ọ̀rọ̀ yìí ló sọ níbi ìpàdé oníròyìn kan tó wáyé ní ọjọ́ Ẹtì òpin ọ̀sẹ̀ yìí,

Ṣoyinka sọrọ yii lọfiisi rẹ niluu Eko, lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lọjọ Ẹti, Furaidee yii.

Ọkunrin naa ni ko si idi kan pato ti wọn tori ẹ mu Sunday Igboho sahaamọ, o ni ko huwa ọdaran kan, ko si si ẹsun to lagbara kan ti wọn ka si i lẹsẹ.

“Mi o le gbagbọ pe Sunday Igboho dẹṣẹ kan ju pe o sọrọ ta ko bawọn ọbayejẹ Fulani ṣe n ṣakọlu sawọn eeyan rẹ lọ. Jẹẹjẹ lo si maa n ṣe iwọde rẹ lati fi ero rẹ han. Ki lo waa buru ninu iyẹn, mi o ri iwa ọdaran kan ninu ohun ti Sunday Igboho ṣe.

Ti pe o loun o fẹ kawọn eeyan oun ba Naijiria ṣe mọ, pe oun fẹ ka daro ni, iyẹn ki i ṣe ẹṣẹ, ko si siwa ọdaran kan ninu ohun to ṣe. Keeyan loun o fẹẹ ba orileede kan lọ mọ ki i ṣe ẹṣẹ, niwọn igba ti tọhun ba ti n beere wọọrọwọ lai fa ijangbọn kan.”

Ṣoyinka ni oun parọwa sijọba orileede Bẹnẹ atawọn agbofinro wọn lati yọ okun lọrun Sunday Igboho, ko le maa ba irinajo rẹ lọ.

Ṣe lati ọjọ kọkandinlogun, oṣu keje, lawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ agbaye kan ti fi pampẹ ofin mu Sunday Igboho ati iyawo rẹ, Rọpo, ni papakọ ofurufu to wa niluu Cotonou, wọn ni wọn lufin immigireṣọn awọn, ṣugbọn lọjọ keji ni wọn ti fi iyawo naa silẹ, lẹyin ti wọn ti foju wọn bale-ẹjọ, latigba naa si ni Ọgbẹni Sunday ti wa lakata wọn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo Fẹ́mi Akínṣọlá Ọ̀fọ́n àn tọ̀ sí gbẹ̀gìr…