Home ÀKỌ̀TUN Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - August 2, 2021

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́

Ọrẹ Òtítọ́jù

Òkú kò mọye tí wọ́n n ra agọ̀, lọ̀rọ̀ àwọ́n bàṣèjẹ́ àwùjọ nígbà mí-ìn pẹ̀lú ìṣesí wọn sí dúkìá ìlú.
Ní báyìí, àwọn ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí alálágbra láti mọ àwọn olubi tó kọ lu iléeṣẹ́ rédíò ìjọba àpapọ̀,Amúlùúdùn FM, tí wọ́n sì ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ dúkìá jẹ́ níbẹ̀.

Eto aabo ipinlẹ Ọyọ dẹnu kọlẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ ta a lo tan yii, pẹlu bi awọn amookunsika ẹda kan ṣe dihamọra ija, ti wọn si kọ lu ileeṣẹ redio ijọba apapọ ilẹ yii, iyẹn Amuludun FM, to wa laduugbo Mọniya, n’Ibadan.

Pato n to si fa ikọlu ọhun ko ti i ye ẹnikẹni di baa ṣe n wi yii. Ẹnikan to ta akọroyin wa lolobo iṣẹlẹ yii fidi ẹ mulẹ pe ara ija lawọn ọbayejẹ ọhun mu lọ sileeṣẹ ijọba yii nitori niṣe ni wọn dihamọra pẹlu awọn nnkan ija oloro mi-in lọọ huwa apa ọhun.

Awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ redio yii sọ fawọn oniroyin pe ọkẹ aimọye dukia bii ọkọ ayọkẹlẹ, ferese ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn bajẹ nileeṣẹ redio ọhun.

Ọga agba Redio Amuludun, Ọgbẹni Niyi Dahunsi, fidi iroyin yii mulẹ. O ni awọn ti ranṣẹ pe awọn eleto aabo lati waa daabo bo awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ naa nigba ti awọn agbofinro n ṣewadii lọwọ lati mọ awọn basejẹ eeyan to huwa gbese ko kan mi.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo Fẹ́mi Akínṣọlá Ọ̀fọ́n àn tọ̀ sí gbẹ̀gìr…