Home ÀKỌ̀TUN Níbi ètò ìdìbò abẹ́lé l’Ékìtì, ẹnìkan kú, ọ̀pọ̀ ṣeṣe,
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 31, 2021

Níbi ètò ìdìbò abẹ́lé l’Ékìtì, ẹnìkan kú, ọ̀pọ̀ ṣeṣe,

Níbi ètò ìdìbò abẹ́lé l’Ékìtì, ẹnìkan kú, ọ̀pọ̀ ṣeṣe,

Ọrẹ Òtítọ́jù

Àdúrà kí wọ́n má fẹ̀jẹ̀ ẹ wa ṣètùtù ìlù náà la ó máa gbà ní gbogbo ìgbà,ṣùgbọ́n kò jọ pé ẹ̀bẹ̀ àdúrà yìí jọ fún ọ̀dọ́mọkùnrin ẹni ọdún mẹ́tàlélógún kan tí wọ́n pé orúkọ rẹ̀ ní Jide, bó ṣe kú lójijì, nígbà tí àwọn mí-ìn tún fara pa níbi ìjà kan tó wáyá lásìkò ètò ìdìbò abẹ́lé tó wáyé nípìnlẹ̀ Èkìtì lọ́jọ́, Sátidé.

Wọọdu kẹwa, ni agbegbe GRA, niṣẹlẹ naa ti waye niluu Ado-Ekiti.

Alaye ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa to wa nibi iṣẹlẹ yii ṣe fun akọroyin wa ni pe ọmọkunrin naa ti mu ọti ati egboogi oloro yo, lẹyin to si ti wa lẹrẹ lo bẹrẹ ariyanjiyan pẹlu awọn ẹlẹgbẹ rẹ miiran to wa ni ibudo idibo naa, eyi to pada di ija nla.

Wọn ni niṣe ni Jide pa igo ọti to gbe wa si ibi eto idibo naa, to si fẹẹ gun ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ toun na wa nibẹ.

Lẹyin iṣẹju diẹ la gbọ pe ẹnikan gun Jide nikun, ti wọn si sare gbe e lọ si ileewosan, nibi tawọn dokita ti fidi rẹ mulẹ pe o ti jade laye.

Iroyin ti o tẹ wa lọwọ lati Ado-Ekiti ati awọn ilu miiran ti eto naa ti waye sọ pe niṣe ni awọn alatilẹyin Gomina Fayẹmi fẹnu ko si pe ki wọn fa ẹni kan ṣoṣo kalẹ ni agbegbe kọọkan eyi ti wọn n pe ni (Consensus candidate). Ṣugbọn awọn alatilẹyin Oludamọran Aarẹ Buhari lori eto oṣelu, Ọgbẹni Babafẹmi Ojudu, yari pe awon ko ni i gba igbesẹ bẹẹ.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe loootọ ni eeyan kan ku nigba ti ija bẹ silẹ nibi ti wọn ti n ṣe eto idibo naa. “A ṣẹṣẹ gba ipe pajawiri lati ọdọ DPO to wa ni agbegbe naa ni, Alaga kansu ijọba ibilẹ Ado-Ekiti, Iyaafin Ọmọtunde Fajuyi naa ti pe wa.

“A ti bẹrẹ iwadii to daju lori iṣẹlẹ naa, wọn si ti gbe oku ọmọdekunrin naa lọ si ile igbokuu-pamọ si to jẹ ti ijọba ni Ado-Ekiti.

Nigba ti akọroyin beere boya wọn ti ri ẹnikẹni mu lori iku oloogbe naa, Alukoro ni awọn ko ti i ri ẹnikẹni mu, o ṣeleri pe oun yoo pada pe akọroyin wa lati fun un wọn labọ bi awọn ba ri ẹnikẹni mu lori iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo Fẹ́mi Akínṣọlá Ọ̀fọ́n àn tọ̀ sí gbẹ̀gìr…