Home ÀKỌ̀TUN Sínkún l’àwọn jàndùkù ajínigbé mú bábá tó gbé owó ìtúsílẹ̀ akẹ́kọ̀ọ́ wá
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 25, 2021

Sínkún l’àwọn jàndùkù ajínigbé mú bábá tó gbé owó ìtúsílẹ̀ akẹ́kọ̀ọ́ wá

Sínkún l’àwọn jàndùkù ajínigbé mú bábá tó gbé owó ìtúsílẹ̀ akẹ́kọ̀ọ́ wá

Ọrẹ Òtítọ́jù

Bí ká sọ pé ó soore se ni
o,bí ká sì sọ pé ó gbèjà ìlú dáráàÀ fi bí eré orí ìtàgé lọ̀rọ̀ dà bí àwọn jàndùkú ajínigbé ti mú ẹni tó gbówó ìtúsílẹ̀ fáwọn ọgọ́rùn ún akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ Salihu Tanko Islamic Secondary School nílùú Tegina ní ìpínlẹ̀ Niger mọ́lẹ̀.

Iroyin sọ pe awọn janduku ọhun ni owo itusilẹ ti baba ọhun ko wa ko pe lo jẹ ki awọn mu un mọlẹ.

Iroyin ṣalaye pe awọn obi awọn akẹkọọ naa ti da ẹgbẹẹgbẹrun owo dọla fun itusilẹ awọn akẹkọọ ọhun.

O ti to bi oṣu meji bayii tawọn ajinigbe ti gbe awọn akẹkọọbinrin sa lọ nipinlẹ Niger.

Ọga ile ẹkọ naa sọ pe o yẹ kawọn ajinigbe le tu awọn akẹkọọ naa silẹ lẹyin ti wọn ti gba ẹgbẹrun marunlelaadọrin owo dọla tii ṣe ọgbọn miliọnu naira.

Ṣugbọn o ni ọrọ ti polukuru musu bayii lẹyin ti wọn mu baba to gbowo lọ fun wọn mọlẹ.

Iru nnkan bayii ko wọ pọ pẹlu awọn ajinigbe lorilẹede Naijiria.

O ti le ni ẹgbẹrun kan akẹkọọ tawọn ajinigbe ti ji lọ lawọn ile ẹkọ girama ni Naijiria lati oṣu kejila ọdun 2020 di akoko yii.

Ọpọlọpọ wọn lo si wa ni akata awọn ajinigbe pawo yii titi di asiko yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo Fẹ́mi Akínṣọlá Ọ̀fọ́n àn tọ̀ sí gbẹ̀gìr…