Home ÀKỌ̀TUN Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - July 25, 2021

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ọjọ́ gbogbo ni tolè, ọjọ́ kan péré ni ti olóhun.
Àwọn ìgìrìpá mẹ́ta kan, Aanu Ibikunle, Rasheed Bisiriyu ati Adebọwale Dada,jẹ́ onísọ̀kan ìmọ̀ ìdigunjalè . Ohun tó wìn wọ́n sí ọ̀hún náà ni wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n kó obìnrin oníṣòwò kan tí orúkọ rẹ̀ n jẹ́ Tọpẹ Alabi ní papámọ́ra, tí wọ́n sì gba owó nla lọ́wọ́ ọ rẹ̀ lọ́jọ́ kejìlélógún, oṣù keje yìí, lágbègbè Oke-Ore, Atan-Ọta, ní ìpínlẹ̀ Ogun.

Ipe ‘ẹ gba wa’ lo de etiigbọ DPO teṣan Atan-Ọta, CSP Abọlade Ọladigbolu, pe awọn adigunjale ti bo ṣọọbu obinrin oniwosiwosi ati nnkan mimu kan, wọn si ti gba owo nla lọwọ rẹ. Alẹ, ni nnkan bii aago mẹwaa ku iṣẹju mẹẹẹdogun si ni iṣẹlẹ naa n waye.

Awọn ọlọpaa lọ sibẹ lati mu awọn ole naa ṣinkun, ṣugbọn niṣe lawọn adigunjale yii doju ija kọ wọn, gẹgẹ bi Alukoro wọn, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe wi. Ṣugbọn nigba ti awọn ọlọpaa kọju ija si wọn bo ṣe yẹ ko ri, kia ni wọn mura ati sa lọ.

Nibi ti wọn ti fẹẹ fẹyin rin naa lawọn agbofinro ti mu awọn mẹtẹẹta, iyẹn Aanu; ẹni ọdun mejilelọgbọn,Rasheed; ẹni ọdun mejilelogun ati Adebọwale; ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn.

Lara awọn nnkan tawọn ọlọpaa ba lọwọ wọn ni ibọn ilewọ ibilẹ kan, ọta ibọn meji ti wọn ko ti i yin atawọn ogun ibilẹ loriṣiiriṣii.

Wọn ti ko wọn lọ sẹka itọpinpin to lagbara, ọga ọlọpaa CP Edward Ajogun si gba awọn araalu nimọran lati maa tete fi ohun to ba n ṣẹlẹ lagbegbe wọn to ọlọpaa leti, eyi ni yoo jẹ ki aṣiri awọn afookun sebi o tete maa tu faraye.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo

IPOB láwọn ò fẹ́ àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo Fẹ́mi Akínṣọlá Ọ̀fọ́n àn tọ̀ sí gbẹ̀gìr…