Home ÀKỌ̀TUN Wọ́n ti taari Sunday Igboho sílé-ẹjọ́ ní Kotonú
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 5 days ago

Wọ́n ti taari Sunday Igboho sílé-ẹjọ́ ní Kotonú

Wọ́n ti taari Sunday Igboho sílé-ẹjọ́ ní Kotonú

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àwọn àgbà ní bí ọ̀rọ̀ nlá kò bá tíì tán, èèyàn nlá náà ò kúkú ní-ín sinmi àròyé n ló bí ìròyìn tó n rú túhú bí èèfin onígi lásìkò yìí pé wọ́n ti gbé gbajú-gbajà ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn tó n jà fún ìran Yorùbá nnì, Olóyè Sunday Adeyẹmọ tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn mọ̀ sí Sunday Igboho, lọ sí ilé-ẹjọ́ gíga kan ní ìlú Cotonou, lórílẹ̀- èdè Benin.

Ilé-ẹjọ́ kan tí wọ́n n pè ní Judicial Service Benin, tó wà ní Rue 447, Cotonou, Benin 02BP2004, ni wọ́n gbé e lọ.

Ọ̀kan lára ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án ni pé ó fẹ́ fi ayédèrú ìwé ìrìnnà Nàìjíríà rin ìrìnàjò sílẹ̀ òkèèrè.

Àwọn agbẹjọ́rò tí wọ́n jẹ́ ọmọ Nàìjíríà tí wọ́n wà láwọn Orílẹ̀ bíi France, London, Germany àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n ti péjú sílé-ẹjọ́ ọ̀hún látí ríi pé nnkan kò pinyìnkìn mọ́ gbajú-gbajà ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn ọ̀hún lọ́wọ́.
Bí nnkan bá ṣe n lọ, Ìròyìn Òwúrọ̀ yóó jábọ̀ ọ òkodoro.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…