Home ÀKỌ̀TUN À fi kí ìjọba àpapọ̀ ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho- Ladọja
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 6 days ago

À fi kí ìjọba àpapọ̀ ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho- Ladọja

À fi kí ìjọba àpapọ̀ ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho- Ladọja

Ọrẹ Òtítọ́jù

Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ẹni tí a kò fẹ́, ààlọ̀ kò ràn án, ṣùgbọ́n wọ́n ní kò ní-ìn burúburú títí kó mọ́ ku ẹnìkan mọ́ ni, látàrí i bí ìjọba Orílẹ̀-èdè Benin ṣe mú ajìjaàgbara ilẹ̀ Yorùbá nnì, Olóyè Sunday Adéyẹmọ (Sunday Igboho), tí wọ́n sì n múra láti fà á lé ìjọba Nàíijíríà lọ́wọ́ fúnyà jẹ, Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ tẹ́lẹ̀, Sẹ́nítọ̀ Rashidi Adewọlu Ladọja, ti gba ìjọba àpapọ̀ nímọ̀ràn láti tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́ lórí ọ̀rọ̀ ọkùnrin ajìjaàgbara ọ̀hún.

Lasiko to n gba awọn oniroyin lalejo fun ọdun Iléyá lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, lo sọrọ naa nile ẹ to wa laduugbo Bodija, n’Ibadan.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Aiṣedeede ijọba apapọ naa lo sọ ọ di olokiki, paapaa lori ọrọ Igangan. Gbogbo eeyan lo ti sọ ọ, Alaafin paapaa sọ ọ, pe nigba ti wọn ba mu ẹnikan fun iwa ọdaran, paapaa bi ẹni naa ba jẹ Fulani, niṣe laṣẹ maa wa latoke pe ki wọn fi onitọun silẹ.

“Wọn pa ọpọ eeyan lagbegbe Ibarapa. Aarin ọsẹ kan sira wọn ni wọn pa Dokita Aborode ati obinrin kan to ni ileepo lagbegbe yẹn. Bẹẹ ni wọn ṣe pa ogunlọgọ eeyan, ṣugbọn ti wọn ko ri ẹnikẹni mu ninu awọn to hu awọn iwa ọdaran wọnyẹn.

“Eyi ni Sunday Igboho ta ko pe ko yẹ ko maa ri bẹẹ. Ohun to sọ ọ dolokiki niyẹn.

“Ijọba apapọ ni lati ṣe pẹlẹpẹlẹ lori ọrọ yii nitori ti wọn ba mu Sunday Igboho, aimọye iru eeyan bii tiẹ lo wa nigboro kaakiri.

“Ko sẹni to mọ nnkan to maa ṣẹlẹ si Igboho ni awọn ijọba ilẹ Benin ba fa a le ijọba orileede yii lọwọ. Gẹgẹ bi Nnamdi Kanu ṣe jẹ olori fawọn kan nilẹ Ibo, bẹẹ ni Sunday Igboho naa ti di aṣáájú fawọn kan naa bayii.

Bi Kanu ṣe wa yẹn, ba a fẹ, ba a kọ, o ti di olori awọn kan. Gẹgẹ bẹẹ ni Igboho naa ti ṣe di olori fawọn kan bayii. Ti ijọba ko ba ṣe e jẹẹjẹ, o le di nnkan ti awọn ajijagbara bii Kanu ati Igboho fi maa pọ si i lorileede yii .

“Bi wọn ṣe n dariji awọn Boko Haram, ki wọn dariji Kanu ati Igboho naa. Bii ẹgbẹrun kan awọn ikọ Boko Haram (ìkọ to n fẹmi awọn eeyan ṣofo nipinlẹ Borno) to wa latimọle kan ṣaa nijọba apapọ tu silẹ ti wọn yọnda fun ijọba Borno lọsẹ to koja. Ohun to ba mu ki ijọba maa dariji awọn Boko Haram to n fẹmi awọn eeyan ṣofo, o yẹ ki wọn le fi Igboho ati Kanu naa silẹ.”

Nigba to n sọrọ lori ọrọ ominira ti awọn kan n ja fun, Ladọja to tun jẹ Osi Olubadan tilẹ Ibadan, ṣalaye pe “ariwo ti awa Yoruba n pa lori ọrọ ominira yii ti pọ ju, awọn ara Oke-Ọya paapaa naa ti n mura silẹ de ominira, ṣugbọn eyi ti awa fi n pariwo lasan yii, awọn ti n ṣiṣẹ silẹ labẹnu lori bi wọn yóò ṣe máa ṣètò ara wọn nigba ti kaluku ba da duro tan, ki i ṣe pe wọn kan n pariwo bii tiwa.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…