Home ÀKỌ̀TUN Pe ìpàdé àlàfíà pẹ̀lú àwọn tó n pè fúnOrílẹ̀ mí-ìn –Ọbásanjọ́
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 7 days ago

Pe ìpàdé àlàfíà pẹ̀lú àwọn tó n pè fúnOrílẹ̀ mí-ìn –Ọbásanjọ́

Pe ìpàdé àlàfíà pẹ̀lú àwọn tó n pè fúnOrílẹ̀ mí-ìn –Ọbásanjọ́

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé àwọn àgbà ní igbá pẹ̀lẹ́ kíì fọ́, bẹ́ẹ̀ àwo pẹ̀lẹ́ kan kìí fàya.
Ààrẹ ilẹ̀ ẹ wa tẹ́lẹ̀rí, Olóyè Olúṣẹ́gunỌbásanjọ́, ti ṣèkìlọ̀ pé àfàìmọ̀ kí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n n pariwo pé àwọn máa ya kúrò lórílẹ̀èdè Nàìjíríà lọ̀ọ́ dá Orílẹ̀ ẹ̀yà tiwọn sílẹ̀, má mu ìjọba lómi gidi, bẹ́ẹ̀ ó sì lè kọjá ohun tí apá ìjọba àpapọ̀ yóó káh, pẹ̀lú bí wọ́n ṣe gùn lé fífọwọ́ líle mú ọ̀rọ̀ ọ̀hún.

Ọbásanjọ́ ní òun kò lòdì sí kí Ààrẹ Muhammadu Buhari ṣèpàdé àlàfíà pẹ̀lú àwọn ajìjàgbara tó n fọnrere ìyapa yìí, ó ní ọ̀nà tóun mọ̀ tó dáajù lọ láti bójútó awuyewuye ọ̀hun nìyẹn.

Lasiko to n dahun ibeere tawọn oniroyin ilu eebo kan, tileeṣẹ Newsweek bi i l’Ọjọbọ, yii, lori ipo torileede Naijiria wa, l’Ọbasanjọ sọrọ naa.

Ọbasanjọ ni “Mi o rohun to buru ninu ki Buhari ṣepade pẹlu Nnamdi Kanu, tabi awọn eeyan mi-in ti wọn n sọrọ yiya kuro lara Naijiria, mi o le ta ko iru igbesẹ bẹẹ, kaka bẹẹ, mo maa fun wọn niṣiiri lati ṣe bẹẹ ni.

“To ba jẹ emi ni Aarẹ ni, niṣe ni ma a pe Kanu, ma a tun pe awọn mi-in ti ọrọ wọn jọra pẹlu tiẹ, awọn ẹlẹgbẹ ẹ, ma a si bi wọn leere pe: ‘Ki niṣoro yin gan-an, ki lẹ fẹ’? Ki i ṣe Kanu lati ilẹ Ibo nikan o, mo maa pe awọn ajijagbara to wa lawọn agbegbe mi-in pẹlu.”

Aarẹ nigbakan ri ọhun tun sọ pe bawọn ologun ṣe fẹẹ fọwọ lile mu ọrọ yii lewu, ko le mu ojutuu wa, bẹẹ si lọrọ awọn to fẹẹ ya kuro naa ko le mu ojutuu wa. O ni ọwọ pẹlẹkutu lo yẹ kijọba fi mu ọrọ ọhun, tori iṣoro to le mu Naijiria lomi ni.

“A gbọdọ pese iṣẹ to to fawọn ọdọ wa, iṣẹ gidi, ka si fẹsẹ wọn le ọna ati la, ka pese ọjọ ọla to nitumọ fun wọn, ki ireti wọn fun ọjọ ọla rere le duro. Ko sọna abayọ mi-in.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…