Home ÀKỌ̀TUN Lóríi bíríìjì Ọtẹdọla, ẹni kan ku, ọ̀pọ̀ èèyàn ṣèṣe ,bí kọ̀nténà ṣe rún ọkò ayọ́kẹ́lẹ́ méjì jégéjégé
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 7 days ago

Lóríi bíríìjì Ọtẹdọla, ẹni kan ku, ọ̀pọ̀ èèyàn ṣèṣe ,bí kọ̀nténà ṣe rún ọkò ayọ́kẹ́lẹ́ méjì jégéjégé

Lóríi bíríìjì Ọtẹdọla, ẹni kan ku, ọ̀pọ̀ èèyàn ṣèṣe ,bí kọ̀nténà ṣe rún ọkò ayọ́kẹ́lẹ́ méjì jégéjégé

Ọrẹ Òtítọ́jù

Àdúrà a kí á mórí délé, ká má ràá sájò ní ọ̀pọ̀ tó bá rìnrìn àjò máa n ṣe ṣùgbọ́n kò dà bí ẹni pé àdúrà yìí ṣẹ mọ́ àwọn ìdílé kan tó lùgbàdìẹ ìjànbá ọkọ̀ lára bi ó ṣe jẹ́ pé ẹsẹ̀ kan-ayé ẹsẹ̀-kan-ọ̀run ni èèyàn mẹ́ta, títí kan dẹ́rẹ́bà tó wa ọkọ̀ ààgbé tó pọn kọ̀nténá sẹ́yìn kan ṣì wà báyìí nílé ìwòsàn tí wọ́n gbé wọn lọ, látàrí bí kọ̀nténá náà ṣe já bọ́ lu àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ méjì lóríi bíríìjì Ọtẹdọla, ní ìpínlẹ̀ Èkó, lọ́jọ́ Àìkú ọ̀sẹ̀ yìí, tó sì ṣekú pa ẹni kan lójú-ẹsẹ̀.

Iṣẹlẹ yii la gbọ po waye lọsan-an ọjọ naa, wọn ni ibi tawọn ọkọ ti n pẹwọ fun awọn kọnkere ti awọn to n tun apa kan biriiji naa ṣe ko saarin titi ọhun ni kọntena to wa lẹyin ọkọ ajagbe kan ti re bọ lojiji, to si run awọn ọkọ ayọkẹlẹ meji to wa lẹgbẹẹ rẹ womuwomu. Nọmba awọn ọkọ ayọkẹlẹ naa ni Lagos JJJ 28 FR ati Lagos BDG 597 CY.

Ọgbẹni Nosa Okunbor, Alukoro fun ileeṣẹ to n ri si ọrọ pajawiri nipinlẹ Eko, Lagos State Emergency Management Agency (LASEMA), sọ nipa iṣẹlẹ ọhun ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Sannde pe awakọ tirela to gbe kọntena naa fara pa gidi, ibi ti wọn si ti n gba itọju pajawiri lawọn gbe e lọ, pẹlu awọn meji mi-in ti wọn fa yọ ninu awoku ọkọ ayọkẹlẹ naa, o ni wọn wa ni ọsibitu Trauma Centre, to wa lẹgbẹẹ ileeṣẹ awọn ẹsọ alaabo oju popo (FRSC) nitosi Too-geeti ọna Eko s’Ibadan.

O ni o ṣe ni laaanu pe ọkan ninu awọn dẹrẹba ọkọ ayọkẹlẹ naa ku loju-ẹṣẹ, o ni Ọgbẹni Lawal ni wọn porukọ ẹ, awọn mọlẹbi ẹ si ti yọju lati gba oku ẹ, ki wọn le lọọ sin in.

Bakan naa lo ni awọn oṣiṣẹ ajọ LASEMA ti wọ awọn awoku ọkọ ọhun ati kọntena to gun lẹsẹ bata ogoji to ja bọ naa kuro laarin titi, ki wọn ma baa ṣediwọ fun lilọ bibọ ọkọ.

O lo anfaani naa lati parọwa fawọn onimọto lati maa fẹsọ ṣe loju popo, paapaa lasiko pọpọṣinṣin ọdun Ileya to wọle yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…