Home ÀKỌ̀TUN A ò fòfin de ìsọwọ́ṣiṣẹ́ akọ̀ròyìn o—Femi Gbajabiamila
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 2 weeks ago

A ò fòfin de ìsọwọ́ṣiṣẹ́ akọ̀ròyìn o—Femi Gbajabiamila

A ò fòfin de ìsọwọ́ṣiṣẹ́ akọ̀ròyìn o—Femi Gbajabiamila

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé oníkálùkù ló lórúkọ tó n jẹ́,àti ìtàn tó fẹ́ fi orúkọ rẹ̀ kọ lásìkò tíẹ̀,agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣòfin, Femi Gbajabiamila ti sọ pé òun kò ní-ín lọ́wó sí àbádòfin kan tó n gbèrò láti fòfin de àwọn akọ̀ròyìn lẹ́nu iṣẹ́ ẹ wọn.

Gbajabiamila sọ pe irufẹ abadofin bẹẹ ko le di ofin labẹ iṣakoso oun ninu ile naa.

Ṣaaju ni ẹgbẹ awọn to ni iwe iroyin, NPAN, ẹgbẹ awọn ọga agba nidii iṣẹ iroyin, NGE to fi mọ ẹgbẹ awọn akọroyin ti kọkọ ṣe ifẹhonuhan.

Won ṣe e niwaju awọn iwe iroyin kan lodi si abadofin kan ti yoo maa ṣakoso iṣẹ wọn, eyi to kede owo itanra nnkan bii miliọnu marun un naira fun awọn to ba tapa si ofin naa.

Lara awọn iwe iroyin ni Najiiria to lamilaaka to kopa ninu ifẹhonuhan naa ni iwaju iwe iroyin wọn ni Punch, Vanguard ati Guardian wa.

Gẹgẹ bi ohun ti gbajabiamila sọ, awọn yoo ṣe atunṣe awọn abala to n da wahala silẹ ninu abadofin naa, tabi ki wọn yọ abala naa kuro patapata.

Gbajabiamila lo fi ọrọ naa lede lasiko to n sọrọ nibi ayẹyẹ kan niluu Abuja.

O ni oun ti ba ẹni to ṣagbatẹru abadofin naa sọrọ, ati pe oun ti ni ki wọn fi ẹda rẹ ṣọwọ si oun fun ayẹwo.

Agbẹnusọ ile naa ni “Emi ko ni wa lara awọn eeyan ti yo ṣofin ti yoo fofi de awọn akọroyin.”

O ni ko yẹ ko si abadofin kankan ti yoo wa siwaju ile, eyi ti afojusun rẹ yoo jẹ lati tẹ ẹtọ awọn akọroyin loju mọlẹ lẹnu iṣẹ wọn.

Gbajabiamila pari ọrọ rẹ pe iyatọ wa laarin abadofin ti yoo fofin de awọn akọroyin ati eyi ti yoo maa ṣakoso iṣẹ wọn.

Lẹyin naa lo ni “Emi gẹgẹ bii agbẹnusọ ile ko ni gbe ofin kankan kalẹ ti yoo fofin de awọn akọroyin.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…