Home ÀKỌ̀TUN Ẹgbẹ́ alátakò PDP gan ti di akúrẹtẹ̀–Femi Adesina
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 2 weeks ago

Ẹgbẹ́ alátakò PDP gan ti di akúrẹtẹ̀–Femi Adesina

Ẹgbẹ́ alátakò PDP gan ti di akúrẹtẹ̀–Femi Adesina

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lojú tí hà há
mú wòye ọ̀rọ̀,bí ìṣẹ̀lẹ̀ bá n ṣẹ̀ nínú ìlú.
Olùdámọ̀ràn fún Ààrẹ Muhammadu Buhari lórí ètò ìròyìn, Femi Adesina ti kéde pé Ààrẹ ti bínú tán sí àwọn èèyàn tó n dá wàhálà sílẹ̀ lórílẹ̀èdè yìí.

O ni awọn agbebọn, ikọ mujẹmujẹ, ọdaran, ajinigbe atawọn to n pe fun iyapa Naijiria lo ti n kan ni ẹṣẹ, ti gbogbo wọn si ti n gbe imu ẹlẹjẹ kiri bayii.

Femi Adesina woye ọrọ yii ninu ọrọ apilẹkọ rẹ to kọ nipa ipo ti Naijiria wa, eyi to gbe si oju opo Facebook rẹ.

O ni ni kete ti wọn fi okun oye ologun tuntun wọ olori ikọ ọmọ ogun ni Naijiria, Farouk Yahaya, lo ti kede pe gbogbo awọn adarugudu silẹ ni Naijiria ni wọn n ran lọ sọdọ Ọlọrun lati lọ dahun awọn iwa ọdaran ti wọn hu.

Adesina ni ọjọ idajọ yii yoo maa tẹsiwaju titi ti orilẹede Naijira yoo fi di afọmọ lọwọ awọn iwa aidaa gbogbo, eyi to tumọ si ede tuntun ti Buhari n fọ jade.

O salaye pe Buhari tẹti bẹlẹjẹ lati gbọ ẹdun ọkan alaga ajọ eleto idibo nilẹ yii, Ọjọgbọn Mahmoud Yakubu, to n gbarata pe bi wọn ba tẹsiwaju lati maa ba awọn ohun eelo idibo jẹ, yoo lewu fun eto idibo lọjọ iwaju.

“Gẹgẹ bii baba ti idunkooko wa fun ile rẹ yoo ti se, o kaanu awọn to n ba nnkan jẹ lorilẹede yii, to si ni awọn ti awọn jagun abẹle fun ọgbọn osu ko ni maa wo wọn niran, ki wọn yiwọ ọkọ Orilẹ pin yii .

Idi ree to fi ni “laipẹ laijinna a ba wọn sọrọ ni ede ti yoo ye wọn.”

Ede ti Buhari fi n ba awọn basejẹ yii sọrọ ti wa di gbas-gbos, ti wọn si n pe Aarẹ ni Olori ẹka ẹkọ nipa ede ni fasiti.”

Bakan naa ni Femi Adesina ni igun kọọkan ni orilẹede yii lo ti wa n gbọ ede Buhari yekeyeke bayii, o ni kii se awọn ọdaran nikan amọ ẹgbẹ oselu alatako PDP pẹlu, ti n gbọ ede Aarẹ yekeyeke.

“Ni ẹka oselu, ẹgbẹ PDP ti n di ahoro, ti ko ba si sọra, ẹgbẹ naa yoo di korofo ko to di ọdun 2023, koroba wọn ti n jo, to si n gba omi gidigidi.

Ni osu diẹ si asiko yii, ẹgbẹ oselu kan yoo maa lagbara siwaju ati siwaju, ti omiran yoo si maa di akurẹtẹ ni ojoojumọ, bi ẹgbẹ oselu kẹta ba tiẹ wa, ko le tii ni ipa kankan.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…