Home ÀKỌ̀TUN Mà á lọ ṣiṣẹ́ lórí orúkọ mi tí wọ́n tàbùkù sí – Kẹmi Adeọsun
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 2 weeks ago

Mà á lọ ṣiṣẹ́ lórí orúkọ mi tí wọ́n tàbùkù sí – Kẹmi Adeọsun

Mà á lọ ṣiṣẹ́ lórí orúkọ mi tí wọ́n tàbùkù sí – Kẹmi Adeọsun

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé èèyàn tí orúkọ rẹ̀ bá bàjẹ́, kò sí àní àní, ìgbésí ayé onítọ̀ùn ló bàjẹ́, ìdí nìyí tí ìdùnnù ńlá fi subú layọ̀ fún Mínísítà fétò ìnáwó nílẹ̀ wa tẹ́lẹ̀rí, Abilékọ́ Kẹmi Adeọṣun, l’Ọjọ́rúù, yìí, látàrí bile-ẹjọ́ gíga ìlú Àbújá kan ṣe dá a láre pé kò pọn dandan kéèyàn níwèé ẹ̀rí jíjẹ́ àgùnbánirọ̀ kí onítọ̀ùn tó ó lè dipò òṣèlú èyíkéyìí mú.

Adajọ Taiwo Taiwo lo dajọ are ọhun ninu ẹjọ kan ti Abilekọ Adeọṣun pe ta ko awuyewuye to waye nipa iwe-ẹri National Youth Service Corps, ti wọn ni ko ni, ko si yẹ ko wa nipo minisita ilẹ wa.

Awuyewuye ọhun lo mu kobinrin naa kọwe fipo silẹ lọdun lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2018.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Taiwo sọ pe ẹni ọdun mejilelogun ni Adeọsun nigba to gboye jade ni Fasiti London, lorileede United Kingdom, nigba to si jẹ ilu oyinbo lọhun-un lo wa, ko si bo ṣe maa kopa ninu iṣẹ isinlu awọn agunbanirọ.

Igba ti olupẹjọ naa yoo fi pada si Naijiria, o ti le lẹni ọgbọn ọdun, eyi fihan pe o ti kọja ọjọ-ori ẹni to le kopa ninu eto isinlu naa.

Adajọ naa loun ṣakiyesi pe ofin ọdun 1979 ni Naijiria n lo lasiko to kawe tan, labẹ ofin naa, ọmọ orileede Britain ni Kẹmi nigba yẹn, ko si pọn dandan fun un lati kopa, tori ofin ọhun ko faaye gba keeyan jẹ ọmọ orileede meji papọ lẹẹkan naa.

Adajọ Taiwo fọba le e pe eeyan niwee ẹri NYSC tabi ko ni i ko sọ pe ki wọn maa yan an sipo oṣelu tabi minisita, iyẹn o si dena ẹnikẹni to ba fẹẹ dije fun ileegbimọ aṣofin.

O ni ile-ẹjọ faṣẹ si awọn ibeere mẹrẹẹrin ti olupẹjọ naa beere, kootu naa si da a lare.

Bi wọn ṣe n pari igbẹjọ naa ni Abilekọ Kẹmi Adeọṣun ti fi atẹjade kan lede nipa bi inu rẹ ṣe dun to lori bi Ifa ẹjọ to pe ọhun ṣe fọ’re fun un.

Adeọsun ni ohun to dun mọ oun ninu ju lọ ni bile-ẹjọ ṣe paṣẹ pe ki i ṣe ọran-an-yan koun mu iwe-ẹri fasiti oun wa, tabi koun kopa ninu iṣẹ aṣesinlu awọn agunbanirọ koun too tọ tun fun iyansipo gẹgẹ bii minisita.

“Idajọ yii ti da mi lare kuro ninu abawọn buruku to ba ba mi lori ọrọ yii. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun Ọba, awọn mọlẹbi mi, awọn ọrẹ mi, lọọya mi, Oloye Wọle Ọlanipẹkun ati gbogbo ẹyin ololufẹ mi tẹ ẹ daniyan nipa mi nigba tọrọ yii ṣẹlẹ lọjọsi.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…