Home ÀKỌ̀TUN Alhaji Fatai ń kírun lọ́wọ́ ni wọ́n ta ní ìbọn, tó sì kú
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 3 weeks ago

Alhaji Fatai ń kírun lọ́wọ́ ni wọ́n ta ní ìbọn, tó sì kú

Alhaji Fatai ń kírun lọ́wọ́ ni wọ́n ta ní ìbọn, tó sì kú

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọjọ́bọ ọjọ́ kìnní osù Keje ọdún 2021 ni àwọn òṣìṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS se ìkọlù s’ílé ajìjàgbara tó n pè fún ìdásílẹ̀ Orílẹ̀ Yorùbá, Sunday Igboho.

Níbẹ̀ sì ni wọ́n ti jẹ́wọ́ pé èèyàn méjì ni àwọn gbẹ̀mí lẹ́nu wọn nínú ilé náà látàrí pé wọ́n n dí àwọn lọ́wọ́ láti sisẹ́ àwọn nínú ilé ọ̀hún.

Gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ fún Sunday Igboho, Olayomi Koiki ti sọ lójú òpó Fesibúùkù rẹ̀, orúkọ ẹni àkọ́kọ́ ni Saheed Adisa, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Àdògán.

Àdògán yìí sì ni wọ́n kọ́kọ́ gbé ojú rẹ̀ síta fún aráyé láti ṣèdárò ikú u rẹ̀ bíi akọni ọmọ Yorùba tó jà fún òmìniran ìran rẹ̀.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti n nàgà láti mọ ẹnìkejì tí ẹ̀mí rẹ̀ bọ́ sínú ìsẹ̀lẹ̀ náà.

Níbáyìí, Koiki ti wá bọ́ sójú òpó Sítágíràmù rẹ̀ láti dárò èèyàn kejì tó jáláìsí nílé Igboho láti ọwọ́ àwọn òsísẹ̀ DSS.

Ẹni ọ̀hún ló pè ní Alhaji Fatai.

Gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ Igboho se wí, Alhaji Fatai yìí n kírun lọ́wọ́ ni àwọn òṣìsẹ́ DSS dé, tí wọ́n fìbọn, gbẹ̀mí-in rẹ̀ nífọná fọnṣu.

Ó wá gbàdúrà pé kí Ọlọ́run tẹ́ olóògbé náà sí afẹ́fẹ́ rere, tí ọ̀pọ̀ ọmọ Yorùbá tó dá sí ọ̀rọ̀ náà sì n fi àdúrà ṣègbè ọrun lẹ́yì-in rẹ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…