Home ÀKỌ̀TUN Ọlọ́pàá Ìjọba àpapọ̀ kò gbọdọ̀ mú ẹni tí wọ́n ń wá nípìńlẹ̀ kan láì gbàṣẹ.–Àwọn gómìnà Gúúsù
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 3 weeks ago

Ọlọ́pàá Ìjọba àpapọ̀ kò gbọdọ̀ mú ẹni tí wọ́n ń wá nípìńlẹ̀ kan láì gbàṣẹ.–Àwọn gómìnà Gúúsù

Ọlọ́pàá Ìjọba àpapọ̀ kò gbọdọ̀ mú ẹni tí wọ́n ń wá nípìńlẹ̀ kan láì gbàṣẹ.–Àwọn gómìnà Gúúsù

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ó dà bí ẹni pé ọ̀fọ́àn tọ̀ sí gbẹ̀gìrì báyìí o, bóyá ní oníkálùkù kò ní kó ẹ̀kọ rẹ̀ dání, bí àwọn gómìnà mẹ́tàdínlógún láti agbègbè Gúúsù ilẹ̀ wa ti ṣèpàdé ńlá kan nílùú Èkó, tí wọ́n sì ti pinnu pé ipò Ààrẹ Nàìjíríà gbọ́dọ̀ máa yípo láàrin agbègbè Àríwá àti Gúúsù ni, àti pé nínú ètò ìdìbò gbogbogbòò tó ń bọ̀ lọ́dún 2023 yìí, kò gbọdọ̀ sí Ààrẹ láti ilẹ̀ Hausa, ilẹ̀ Yorùbá àti ilẹ̀ Íbò nìkan ló lè fa Ààrẹ kálẹ̀.

Ọjọ Aje, yii, ni wọn ṣepade ọhun ni gbọngan apero to wa nile ijọba ipinlẹ Eko, eyi to wa ni Alausa, Ikẹja, nipinlẹ naa.

Ninu atẹjade kan ti alaga awọn gomina naa, Ọgbẹni Oluwarotimi Akeredolu ti i ṣe gomina ipinlẹ Ondo sọ pe lara awọn ipinnu wọn ni pe lati asiko yii lọ, ko gbọdọ si ọlọpaa tabi agbofinro eyikeyii lati ẹka ileeṣẹ ijọba apapọ to gbọdọ waa fi pampẹ ofin gbe ẹnikẹni ni awọn ipinlẹ Guusu lai jẹ pe gomina ipinlẹ bẹẹ ba mọ si i ṣaaju, to si yọnda fun wọn.

Bẹẹ ni wọn ṣepinnu pe iṣẹ ti gbọdọ pari ofin to ta ko fifi maaluu jẹko ni gbogbo awọn ipinlẹ mẹtadinlogun ilẹ Guusu ṣaaju tabi ni ọjọ ki-in-ni, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, ki gomina si buwọ lu u.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…