Home ÀKỌ̀TUN E̩ dẹkun ìpè fún ìyapa –YWG
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 3 weeks ago

E̩ dẹkun ìpè fún ìyapa –YWG

Ẹ dẹkun ìpè fún ìyapa –YWG

Ọrẹ Òtítọ́jù

Kò jọ pé ìmọ̀ ọmọ Yorùbá sọ̀kan lórí ìdàsílẹ̀ Orílẹ̀ Yorùbá tí wọ́n ń pè é fún bí àwọn
Ẹgbẹ́ kan tí a mọ̀ sí Yorùbá Welfare Group (YWG), ti késí àwọn ọba Alayé àtàwọn asáájú olóṣèlú nílẹ̀ Yorùbá láti dìde dóòlà aáwọ̀ tó ń wáyé láàrin Sunday Igboho àti èyí tó fi ń dá sí Ìjọba àpapọ̀.

Ẹgbẹ YWG lọgun bẹẹ ninu atẹjade kan to fisita eyi ti aarẹ ẹgbẹ, Comrade Abdulhakeem Adegoke Alawuje fọwọsi to da lori bi DSS se kọlu ile ajijagbara naa ati bi ijọba apapọ se kede pe oun n wa Sunday Igboho.

Ẹgbẹ naa wa rọ ijọba apapọ lati jẹ ki awọn agbaagba nilẹ Yoruba ba Sunday Igboho atawọn ọmọlẹyin rẹ sọrọ lọna ati jẹ ki alaafia jọ̀ba.

O ni eyi yoo tun fun wọn lanfaani lati dẹkun idunkooko lati da ilu ru nipa bi wọn se n pe fun ominira ilẹ Yoruba kuro lara Naijiria.

“A n rọ awọn eekanlu nilẹ Yoruba lati gbe ọrọ ẹsin tabi oselu ti sẹgbẹ kan, ki wọn si fori jin Sunday Igboho lori awọn ẹsẹ to le sẹ wọn.

Amọ ki wọn dide lati gba oun atawọn alatilẹyin rẹ lọwọ awọn ẹsun ti ijọba apapọ fi kan wọn nitori alaafia ilẹ Yoruba se koko.

Gẹgẹ bii ajogunba wa, Ololufẹ alaafia ni awa ọmọ Yoruba, a ko si le kuna ninu ojuse yii, paapaa lori ọrọ to nii se pẹ́lu ilẹ baba nla wa.”

YWG ni oun le fi ọwọ sọya pe ẹya Yoruba ko fara mọ iyapa Naijiria, to si n fẹ orilẹede to wa ni isọkan ati alaafia nibi ti idajọ ododo, ibaradọgba, aisegbe sibikan ati isejọba rere yoo ti wa.

Ẹgbẹ naa wa n fi ọwọ sọya pe oun yoo maa kan si awọn asaaju nilẹ Yoruba lati da si ọrọ to wa nilẹ yii, ki wọn si jẹ ki alaafia jọba nilẹ Yoruba.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi

Ọwọ́ pálábá adigunjalè ẹlẹ́nimẹ́ta tó ja Tọpẹ Alabi lólè owó ṣégi Ọrẹ Òtítọ́jù Ọjọ́ gbogbo…