Home ÀKỌ̀TUN Ọlọ́ọ̀pá ATRS yòó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Èkó dípò SARS
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 17, 2021

Ọlọ́ọ̀pá ATRS yòó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Èkó dípò SARS

Ọlọ́ọ̀pá ATRS yòó yòó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Èkó dípò SARS

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé ètò ààbò ìlú kò ṣe é dágunlá sí, bí èèyàn kò bá fẹ́ fi iná s’órí òrùlé sùn.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ti gbé ikọ̀ tuntun kalẹ̀ tí yóó máa gbógun ti ìdigunjalè lójú pópó jákèjádò ìpínlẹ̀ Èkó.

Orúkọ ikọ̀ náà ni Anti Traffic Robbery Squad tí yóó máa gbógun ti ìdigunjalè lójú pópó papàá lásìkò tí súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ bá wà.

Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Èkó, Hakeem Odumoṣu ti pàṣẹ pé kí àwọn ọlọ́pàá ikọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ ìdánilẹ́kọ́ọ̀ àti ìgbaradì.

Odumoṣu ní láàrin oṣù kẹta sí àsìkò yìí, kò dín ní èèyàn mẹ́tàdínláàdóje tí ọwọ́ ti bà gẹ́gẹ́ bí afurasí adigunjalè inú súnkẹrẹ-fàkẹrẹ nípìńlẹ̀ Eko.

Ó fikún-un pé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Èkó ti dìde ìjà sí àwọn olè tó ń gba tọwọ́ oníǹkan nínú súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀.

Nínú àtẹjáde kan tí alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Èkó, Olumuyiwa Adejọbi fi síta, ó ní Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá nípìńlẹ̀ Èkó ti fi àṣẹ síi pé kí ìdánilẹ́kọ́ọ̀ olóore kóòrè ó máa wáyé fún àwọn ọlọpaa ní ìpínlẹ̀ ọ̀hún.

Ó ní èyí jẹ́ ara ọ̀nà àti leè jẹ́ kí wọ́n wà ní ìgbaradì fún gbogbo ìpèníjà ààbò tó bá ń wáyé nípìńlẹ̀ nàá.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Òkú k…