Home ÀKỌ̀TUN Ààrẹ Buhari gbóríyìn f’áwọn ọmọ ogun Orílẹ̀ yìí fún ìdúró sinsin wọn
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 17, 2021

Ààrẹ Buhari gbóríyìn f’áwọn ọmọ ogun Orílẹ̀ yìí fún ìdúró sinsin wọn

Ààrẹ Buhari gbóríyìn f’áwọn ọmọ ogun Orílẹ̀ yìí fún ìdúró sinsin wọn

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní kúuṣẹ́ ní-ìn mórí onísẹ́ ẹ́ yá ,Ààrẹ Orílẹ̀ yìí Muhammadu Buhari ti ṣe àbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ Borno, tó sì bá àwọn ọmọ ogun tó wà lójú ìjà níbẹ̀ ṣọ̀rọ̀.

Oṣù Kejì, ọdún 2020 ni Ààrẹ lọ sí ìpínlẹ̀ náà kẹ́hìn, níbi tí àwọn ènìyàn ti pariwo “Ba Mayi, ba mayi” ( aò ṣe, aò ṣe mọ́) lé e lórí lásìkò tó ń jáde ní ààfin Emir ìlú Maiduguri.

Ọjọbọ ni Buhari ṣe àbẹ̀wò ọlọjọ kan, nibi to ti gúnlẹ̀ si ibudo awọn ọmọ ogun ofurufu to wa niluu Maiduguri ni nǹkan bi aago mẹwa owurọ.

Gomina ipinlẹ Borno, Babagana Zulum ati awọn Ọga Agba lẹ́nu isẹ ijọba lo si wa nibẹ lati gbalejo rẹ.

Lasiko àbẹ̀wò naa ni Aarẹ ti ba awọn ọmọ ogun sọrọ ni olu ibudo Operation Hadin Kai, ati ọ̀wọ́ keji ileesẹ ologun Naijiria to wa ni Malari Cantonment, Maiduguri.

Ninu ọrọ si awọn ọmọ ogun, Aarẹ sọ pe oun ki wọn fun iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe lati ri i pe Naijiria ko ṣubú si ọwọ àwọn ọta rẹ.

Bakan naa lo ni oun daro iku àwọn ọmọ ogun to ti ku si oju ija igbogun ti igbesunmọmi.

O ni ijọba oun ti n ṣe atunse awọn irin’ṣẹ ologun to ti ba jẹ, to si tun ti ra awọn tuntun mii to, eyi to dé si Naijiria laipẹ yii.

O sọ pe akitiyan wọn lo mu ki alaafia jọba ni Ìwọ̀ Òòrùn Ariwa Naijiria, pẹlu bi wọn ṣe kapa àwọn agbesunmọmi ninu igbo Sambisa, Timbuktu Triangle ati agbegbe Lake Chad.

Yatọ si eyi, Aarẹ sọ pe ijọba ti n gbe igbesẹ lati mu ki awọn eeyan agbegbe naa pada sipo.

Bakan naa ni Aarẹ Buhari tun ṣe ifilọlẹ àwọn iṣẹ́ akanse bi ẹgbẹrun mẹrin ile ti ijọba apapọ kọ si Maiduguri, ati awọn àkànṣe iṣẹ diẹ ti ijọba ipinlẹ naa ṣe.

Ninu atẹjade kan to ti kọkọ fi sita, ni ijọba ipinlẹ Borno ti sọ pe Ààrẹ yoo ṣe ifilọlẹ abala akọkọ ile ẹgbẹrun mẹwa ti ijọba apapọ gbọ bukaata rẹ fún awọn ti ogun Boko Haram sọ di alainilelori ati atipo.

Gomina Zulum sọ pe kikọ àwọn ile naa lo jẹ iru rẹ to tobi julọ ninu awọn ti ijọba apapọ ṣe si awọn ipinlẹ ni Naijiria.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Òkú k…