Home ÀKỌ̀TUN Àwọn ọ̀dọ́ fi ẹ̀hónú hàn lórí wàhálà awakọ̀ èrò n’Íbàdàn
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 16, 2021

Àwọn ọ̀dọ́ fi ẹ̀hónú hàn lórí wàhálà awakọ̀ èrò n’Íbàdàn

Àwọn ọ̀dọ́ fi ẹ̀hónú hàn lórí wàhálà awakọ̀ èrò n’Íbàdàn

Ọrẹ Òtítọ́jù

À n jèkuru ọ̀ràn kó tán, àwọn kọ̀lọ̀rànsí èèyàn kan tún n gbọnwọ́ rẹ̀ sínú àwo bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ dà, bí ohun gbogbo ṣe fọ́júpọ̀ tí ọ̀rọ̀ sì di bóòlọ, kóo yàgò fún mi ni ìrọ̀lẹ́ Ọjọ́rú òní ládùgbóò o Iwo Road nílùú Ìbàdàn, nígbà tí ohun gbogbo dẹnu kọlẹ̀, tí àwọn èèyàn sì n sá àsálà fún ẹ̀mí wọn.

Gẹgẹ bi iroyin to n tẹ wa lọwọ ti wi, awọn ọmọ igbimọ to n se akoso gareeji ọkọ, PMS, eyi ti Alhaji Mukaila, ti ọpọ eeyan mọ si Auxilliary ko sodi, ni wọn fija pẹẹta pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ́ awakọ NURTW, tijọba ipinlẹ Oyo ti fi ofin de.

Bi o tilẹ jẹ pe ko tii si ẹni to le sọ ohun to fa isẹlẹ naa, amọ se ni iro ibọn n dun lakọ-lakọ lagbegbe naa, ti ọrọ si di ẹni ori yọ, o dile.

Gẹgẹ bi ẹnikan ti isẹlẹ naa soju rẹ se salaye fun akọroyin ,o ni kawọn to sẹju pẹ, oku meji ti sun nitori isẹlẹ naa.

Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe se ni awọn igun mejeeji to n kọju ija sira wọn ọhun fọ awọn eroja foonu olowo iyebiye tawọn ontaja n ta nikorita Iwo Road.

Bẹẹ lo ni wọn ba gbogbo ohun ti wọn fi n patẹ ọja wọn jẹ, ti ekufọ igo si kun ilẹ kaakiri agbegbe naa.

Koda, awọn ọdọ ti inu n bi lori isẹlẹ naa ati ẹmi to ba rin, gbe eeyan kan to fara gba ọgbẹ lasiko ti rogbodiyan naa n waye lọ si ọgba Secretariat nilu Ibadan.

Awọn ọdọ naa ti wọn pọ niye, lo duro siwaju ọọ fisi gomina, ti wọn si n pariwo pe awọn fẹ ki gomina Seyi Makinde wa wo itu tawọn eeyan Auxillary pa ni Iwo Road.

Amọ titi di igba ta fi n ko iroyin yii jọ, Gomina Seyi Makinde ko yọju rara si awọn ọdọ naa.

Wayi o, wọn ti ko awọn ọmọ ikọ digboluja Operation Burst ransẹ si Iwo Road lati da alaafia pada si agbegbe naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Òkú k…