Home ÀKỌ̀TUN Òkú TB Joshua yọ sí mi lẹ́yìn ikú rẹ̀ – Jaiye Kuti
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 15, 2021

Òkú TB Joshua yọ sí mi lẹ́yìn ikú rẹ̀ – Jaiye Kuti

Òkú TB Joshua yọ sí mi lẹ́yìn ikú rẹ̀ – Jaiye Kuti

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé a wá lè sọ pé àṣà yorùbà tó sọ nípa àṣẹ̀yìnwáyé jẹ́ irọ́ báyìí pẹ̀lú n tí òṣèrébìnrin, Jaiye Kuti sọ bí ó ti ní òkú olóògbé, Wòlíì Temitope Balogun Joshua, tó jẹ́ olùdásílẹ̀ ilé ìjọsìn Synagogue Church of All Nations, yọ sí òun lẹ́yìn ikú rẹ̀.

Ninu ọrọ to kọ si ori ayelujara Instagram rẹ, Kuti sọ pe iyalẹnu lo jẹ fun oun pe TB Joshua yọ si oun, bo tilẹ jẹ pe oun ko ri loju koroju ri nigba to wa laye.

Ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa ni Woli naa jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgọta.

Oṣerebinrin naa sọ pe nise ni ori oun dide jan-in lasiko ti oku TB Joshua yọ si oun, ti oun si ri to rọra kọja lọ jẹjẹ.

“Mi o ri ri lojukoroju, sugbọn oku rẹ yọ si mi nigba to ku.

Emi nikan ni mo wa ninu yara mi ni ilu Offa, ti mo deede ri to kọja. Ori mi dide. Nkankan to dara wa nipa ẹ̀mí naa.”

“Alaini ni Kristi, sugbọn o bọ́ awọn eniyan, o si n tọju gbogbo eeyan. Bẹẹ ni ìwọTB Joshua naa ṣe fun ọpọlọpọ.
Eeyan meji ni mo mọ to fi aye wọn fun Jesu ni tootọ nipasẹ rẹ̀.”

Jaiye Kuti ni oun gbadura pe ki Ọlọrun tẹ Woli T. B Joshua si afẹfẹ rere.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Òkú k…