Home ÀKỌ̀TUN Ìjọ Synagogue yóò sin TB Joshua ní oṣù kéje ọdún yìí
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 15, 2021

Ìjọ Synagogue yóò sin TB Joshua ní oṣù kéje ọdún yìí

Ìjọ Synagogue yóò sin TB Joshua ní oṣù kéje ọdún yìí

Ọrẹ Òtítọ́jù

Bó ṣe wù kí ẹ̀dá lo sáà tó ní dúníyàn tí a wà yìí, ilé làbọ̀ sinmi oko ni o, torí ẹ kú ìrọ́jú náà ni yóó padà kẹ́yìn gbogbo ẹ kú ewu.

Ìjọ” Synagogue Church of All Nations” nílúù Èkó ti kéde àkókò àti ibi tí wọn yóò sin olùsọ́ àgùtàn wọn tó papòdà láìpẹ̀ yìí, Pásítọ̀ Temitọpẹ Balogun Joshua sí.

Ninu atẹjade kan eyi ti wọn fi sita lọjọ Aje, wọn ni inu ayika olu ile ijọsin naa to wa nilu Eko ni wọn yoo sin wolii TB Joshua si.
“A n gbaradi fun eto isin ọlọsẹ kan ti yoo bẹrẹ ni ọjs karun un si ikọkanla ni iranti igbe aye Wolii TB Joshua.”

Atẹjade naa tun tẹsiwaju pe, “A o sin si ile ijọsin The Synagogue, Church of All Nations (SCOAN) nilu Eko”

Ẹni ọdun mẹtadinlọgọta ni Pasitọ TB Joshua ki o to jade laye lọjọ karun un oṣu kẹfa ọdun 2021 nigba to ku ọjọ diẹ si ọjọ ibi rẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Òkú k…