Home ÀKỌ̀TUN Ẹsẹ̀ ò gbèrò,níbi àfihàn fíìmù ìtàn ìgbèsí ayé Àyìnlá Ọmọwúrà
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 15, 2021

Ẹsẹ̀ ò gbèrò,níbi àfihàn fíìmù ìtàn ìgbèsí ayé Àyìnlá Ọmọwúrà

Ẹsẹ̀ ò gbèrò,níbi àfihàn fíìmù ìtàn ìgbèsí ayé Àyìnlá Ọmọwúrà

Ọrẹ Òtítọ́jù

Hùn, akọni ni yóó máa ṣèdárò lẹ́yìn akọni, èyí
náà ló fàá bí ẹsẹ̀ kò ṣe gbèrò lọ́jọ́ Àìkú, tí ó kọjá, níbi tí wọ́n ti kó fíìmù tuntun kan tí wọ́n pe àkọlé ẹ̀ ní ‘Àyìnlá’ jáde bíi ọmọ tuntun, táwọn èèyàn sì n gbóṣùbà fún Túndé Kèlání àtàwọn òṣèré tó kópa nínú fíìmù tó fítàn nla balẹ̀ ọ̀hún.

Lati nnkan bii aago mẹrin irọlẹ lawọn eeyan ti n de leni eji si Gbọngan igbalejo ile sinima EbonyLife Place, to wa ni Victoria Island, l’Erekuṣu Eko, lọjọ naa, nigba ti yoo si fi di aago mẹfa irọlẹ ti eto naa yoo bẹrẹ, fọfọọfọ ni gbọngan naa ku fun ero rẹpẹtẹ.

Fiimu yii ni wọn fi sọ itan igbesi aye ilu-mọ-ọn-ka akọrin Apala ọmọ bibi ilu Abẹokuta nni, Oloogbe Ayinla Ọmọwura, ti inagijẹ rẹ n jẹ Eegunmọgaji.

Fiimu naa sọ nipa ibẹrẹ igbe aye ‘alujọọnu olorin’ yii, bo ṣe di onirawọ, bo ṣe maa n ri imisi orin rẹ gba, titi kan bi iyawo pupọ ṣe wa lọọdẹ rẹ, bo ṣe gbero lati gbe orin Apala lọ siluu oyinbo.

Fiimu naa tun taṣiiri ohun to fa ija laarin oun ati manija ẹ nigba naa lọhun-un, ati bi ọrọ iku rẹ ṣe waye gan-an.

Ọpọ awọn oṣere ilẹ wa, titi kan awọn to kopa ninu fiimu naa to pesẹ sibi ayẹyẹ ọhun ni Kunle Afọlayan, to kopa ọga ejẹnti to fẹẹ gbe Ayinla ati orin rẹ lọ si London, Lateef Adedimeji, to kopa Ayinla Ọmọwura, Debọ Adedayọ (Mista Makaroni), to kopa Maneja Ayinla.

Awọn mi-in to tun wa nikalẹ nibi afihan sinima naa ni Toyin Abraham (Iya Ire), Mercy Aigbe, Fẹmi Branch, Jumọke Ọdetọla, Bimbọ Ademoye, Tunde Kelani, to jẹ alaṣẹ ileeṣẹ Mainframe Productions to ya simima yii, ati awọn ọjẹwẹwẹ onitiata mi-in.

Banki First Bank ati ileeṣẹ Nigerian Breweries to n pọn ọti bia Trophy lo ṣonigbọwọ sinima ọhun, wọn si ṣeto ipapanu ati ọti lọfẹẹ tawọn eeyan fi gbadun ara wọn.

Bakan naa ni awọn eeyan meji, ọkunrin kan ati obinrin kan jẹ ẹbun ẹni to mura daadaa ju lọ, ọkọọkan wọn ni wọn fun niwee sọwedowo ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (#500,000) gẹgẹ bii ẹbun ti wọn jẹ.

Nigba ti akoko to lati ṣafihan fiimu naa, gbọngan iworan nla marun-un ọtọọtọ ni wọn ti ṣafihan rẹ.

Ṣaaju ati lẹyin ti wọn ṣafihan fiimu naa tan, ọpọ awọn oṣere atawọn ero to waa woran sọrọ iwuri ati idunnu nipa fiimu yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Òkú k…