Home ÀKỌ̀TUN Òmìnira ìran yorùbá la má a fi ‘June 12’ ṣe-Sunday Igboho
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - June 12, 2021

Òmìnira ìran yorùbá la má a fi ‘June 12’ ṣe-Sunday Igboho

Òmìnira ìran yorùbá la má a fi ‘June 12’ ṣe-Sunday Igboho

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé wọn ní bí a há ti ṣe làáwí, ẹnì kan kìí yan àna rẹ̀ lódì.àti ẹlẹ́nu rúnrù ló làmù ìyáarẹ̀.

Ajìjàgbara ọmọ Yorùbá nni, Olóyè Sunday Igboho, ti kéde pé ìwọ́de fún bibéèrè fún Orílèèdè Yorùbá làwọn yóó fi ọjọ́ tí ìjọba yà sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ àyájọ́ ìjọba àwa-ara-wa, June 12, ṣe. Bẹ́ẹ̀ ló rọ ìjọba Ààrẹ Muhammadu Buhari láti má ṣe dí àwọn tó bá jáde fún ìwọ́de náà lọ́wọ́.

Igboho sọrọ yii latẹnu agbẹnusọ rẹ lori eto iroyin, Ọlayẹmi Koiki, ninu fideo kan to n ja ran-in lori ẹrọ ayelujara. O ni kaakiri ilẹ Yoruba ni iwọde yii yoo ti waye ni Satide, ọjọ kejila, oṣu yii.

Igboho ni, ‘A n lo asiko yii lati ke si ijọba Buhari pe ki wọn ma ṣe ṣe ikọlu si ẹnikẹni, ki wọn si ma ṣe jẹ ki itajẹsilẹ waye, nitori bi ohunkohun ba ṣẹlẹ, yoo le gidi gan-an ni.’ Bẹẹ lo ni gbogbo ohun to n lọ ni awọn ajọ agbaye yoo ri.

O fi kun un pe awọn ti ṣetan lati gba ohun to jẹ ẹtọ awọn lọwọ awọn arẹnijẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Òkú k…