Home ÀKỌ̀TUN Èèmọ̀ wọ̀lú! Adigunjalè ya bo Aso Rock l’Abuja
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 11, 2021

Èèmọ̀ wọ̀lú! Adigunjalè ya bo Aso Rock l’Abuja

Èèmọ̀ wọ̀lú! Adigunjalè ya bo Aso Rock l’Abuja

Yínká Àlàbí

Olu ilu orileede Naijiria ni Abuja nigba ti Aso Rock je ibujokoo Aare Mohammadu Buhari. Ibe lo daju ju pe ole ko lee wo sugbon ayipada buruku ti de.
Ojo Alamiisi to koja ni a gbo pe awon adigunjale wo ile Maikano Abdullahi to je ‘Adinistration Officer’ ni adugbo Villa. Ojo Aje ana ni awon adigunjale tun gbiyanju ile Ojogbon Ibrahim Gambari to je ‘Chief of Staff’ si Aare.
Hun-un! “Afefe to fe, to kaso ni iyara, eni to wo tire sorun, ko ma safara”. Eyi ko gbogbo eniyan lominu pe ti adigunjale ba le wo adugbo Aare Buhari, a je wi pe ko si eni ti won ko le digun ja mo ni orileede yii.
Deede aago meta oru ni Ojogbon Gambari ni awon adigunjale naa de odo oun sugbon ti won ko ri nnkankan ko.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àmọ̀tẹ́kùn yẹ kó di ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ láìpẹ́ – Akeredolu

Àmọ̀tẹ́kùn yẹ kó di ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ láìpẹ́ – Akeredolu Ọrẹ Òtítọ́jù Sé wọ́n ní a kìí wí sí…