Home ÀKỌ̀TUN Àbẹ́là jó Kayode Badru pa lásíkò ètò àdúrà pẹ̀lú Wòlí rẹ̀ ní sọ́ọ̀sì
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 9, 2021

Àbẹ́là jó Kayode Badru pa lásíkò ètò àdúrà pẹ̀lú Wòlí rẹ̀ ní sọ́ọ̀sì

Àbẹ́là jó Kayode Badru pa lásíkò ètò àdúrà pẹ̀lú Wòlí rẹ̀ ní sọ́ọ̀sì

Ọrẹ Òtítọ́jù

À fi ògédé ẹni Ọlọ́run bá
kóyọ nìkan ló le móríbọ́ nínú ewu òhun làásìgbò ilé ayé.
Ọrọ ti di ranto lori ẹrọ ayelujara ti oniruuru ariwisi si n boode lẹnu awọn eeyan ilu,lẹyin ti ọdọmọde olowo ati oniṣowo ni ipinlẹ Eko, Kayode Badru ku iku ojiji ni ile ijọsin Celestial Church of Christ ni ilu Eko.

Iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni Ọjọ Aje, Ọjọ Kẹta, Osu Karun un, lasiko to n ṣe eto adura ninu ile ijọsin naa.

Ọkan gboogi ninu awọn agba ni ile ijọsin ti iṣẹlẹ naa ti waye, Imolẹmitan Ojo ni ọpọlọpọ iroyin ofege lo n kaakiri lori iṣẹlẹ naa, ti kii si ṣe otitọ.

Imolẹmitan Ojo to ba akọroyin sọrọ sọ pe pẹlu ibanujẹ ni gbogbo ijọ naa wa pẹlu iṣẹlẹ iku Kayode Badru to jẹ ọmọ ijọ wọn.

Woli ati Oluṣọ agutan ijọ naa, Ebony Felix mọ ara wọn ni nkan bi ọdun meji ṣẹyin, ti o si maa n gbadura fun un ni ọpọ igba.

Brother Imọlẹmitan ni ọpẹ́ ní Kayode Badru ń ṣe pẹ̀lú imọlẹ meje ti o fi n ṣe ọpẹ naa ki o to di wi pe nkan yiwọ.

O ni: ”Funrara Kayode Badru lo tan imọlẹ meje to fẹ fi ṣe ọpẹ ni Ọsan Ọjọ Aje naa, ti o fi dupẹ lọwọ Ọlọrun

”Lẹyin naa ni wọn gba imọlẹ meje naa ni ọwọ rẹ, ti wọn si sunmọ kuro ni ọdọ rẹ, ki Woli Ebony to gbadura fun un to si wọn ‘perfume’ si i lara amọ ko pọju bi o ṣe yẹ lọ”

Imolẹmitan ni: ”Amọ sutana fẹlẹfẹlẹ lo wọ si ara ti ko si si ẹni to mọ bi ina ṣe sọ ni ara rẹ”

”Ti ina fi jo Kayode ni ara ko ju iṣẹju aaya ọgbọn, ti ko si to iṣẹju kan ti awọn eniyan to wa nibẹ fi sare digbadigba lọ bu omi ti wọn si pa ina naa”.

”Wẹrẹ ti iṣẹlẹ naa waye ni wọn si gbe e lọ si ile iwosan ijọba, ti wọn si tibẹ gbe e lọ si ileewosan ti wọn ti n tọju ijamba ina, to si bẹrẹ si ni gba itọju ni Ọjọ Aje ti iṣẹlẹ ọhun waye”.

Arakunrin Imọlẹmitan tun ṣalaye siwaju pe ”Ni Ọjọ Iṣẹgun, ti mo lọ wo o ni ileewosan, alaafia ni o wa ti o si ba awọn eniyan sọrọ.”

“Ni Ọjọọru ti mo pada lọ si ibẹ, Kayode Badru sọ fun mi pe oun jẹun, o jẹ amala to si mu olomiọsan, amọ Ọjọbọ ni wọn sọ fun mi pe o ti jade laye”.

Ni bayii, olusọ naa ti wa ni atimọle ileeṣẹ ọlọpaa ni Panti pẹlu awọn to wa nibẹ nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ni ile ijọsin Celestial Church of Christ ọhun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àmọ̀tẹ́kùn yẹ kó di ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ láìpẹ́ – Akeredolu

Àmọ̀tẹ́kùn yẹ kó di ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ láìpẹ́ – Akeredolu Ọrẹ Òtítọ́jù Sé wọ́n ní a kìí wí sí…